Enfield stabbing: Timothy Adeoye f'ojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn nílùú London

Donovan Allen, 18,

Oríṣun àwòrán, MET POLICE

Àkọlé àwòrán, Donovan Allen, 18,

Ileeṣẹ ọlọpaa ilu London ti fẹsun ipaniyan kan ẹni ọdun mejidinlogun kan, Timothy Adeoye.

Wọn fẹsun kan Adeoye pe o ṣekupa akẹgbẹ rẹ ti oun naa ko tii pe ẹni ogun ọdun, iyẹn Donovan Allen, lẹyin to gun oloogbe naa lọbe pa.

Awọn ọlọpaa ni awọn ṣawari Allen nile kan lagbegbe Ayley Croft, ni Enfield, lọjọ Keje, oṣu Keji, ọdun yii.

Lẹyin naa ni Donovan jade laye, bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ pajawiri gbiyanju lati doola ẹmi rẹ.

Ayẹwo oku rẹ fi han pe Donovan ku lẹyin ti wọn gun lọbẹ lẹẹkan ṣoṣo ni igba aya rẹ.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Wayi o, wọn ti wa fi afurasi naa si atimọle, yoo si foju bale ẹjọ majistreeti to wa ni Wilesden.

Yatọ si ẹsun ipaniyan, wọn tun fi awọn ẹsun mẹta mii kan afurasi ọhun bii igbiyanju lati digunjale, nini ohun ija oloro ni ikawọ, ati fifi abẹ dukoko mọ ẹlomiran laarin ilu.

Donovan Allen,

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ọpọ eeyan n ṣedaro Donovan to jade laye

Awọn mọlẹbi Donovan to di oloogbe naa sọ gbogbo awọn to mọ ọdọkunrin naa lo ni ifẹ rẹ denu.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, ẹbi naa ni o jẹ ẹnikan to dantọ ninu ohun gbogbo to ba n ṣe.

Àkọlé fídíò, Bunmi Akinnanu: Ọlọ́run kìí fún èèyàn méjì ní orin ẹ̀mí kan ṣoṣo, ẹ jẹ́ ká ṣe sùúrù

Wọn ni "Lati ibẹrẹ aye rẹ titi di akoko to dagbere faye, o jẹ ẹnikan to ni ẹran ifẹ lara."

"Bẹẹ ni o maa n gbadura fun gbogbo awọn ọrẹ rẹ ati mọlẹbi rẹ ni aarọ ati ni aṣalẹ."

"A ko le ṣakawe irufẹ ẹni ti Donovan jẹ ati bi a oo ṣe saaro rẹ to."

Àkọlé fídíò, Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun yí n ṣé ní Sierra Leone