Ukraine crisis: Russia ní òun ṣì lè sọ àsọyépọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Ukraine

Ọmogun Russia

Oríṣun àwòrán, TASS/Getty Images

Orilẹ ede Russia ti sọ pe oun si le jiroro pẹlu awọn orilẹ ede Amẹrika at'awọn orilẹede to ti goke agba ni Yuroopu lori aawọ Russia pẹlu Ukraine.

Ninu Ipade kan to waye lori ẹrọ amohunmaworan ni wọn ti sọ fun Aarẹ Vladimir Putin pe ọrọ naa ṣi le ni yanju ninu jijiroro pọ.

Ọrọ yii jade lẹyin ti ọpọ orilẹ ede sọ k'awọn ọmọ ilu kuro ni Ukraine nitori ìbẹrù pe Russia le yin ado oloro sinu afẹfẹ nigba kugba.

Russia ti n sọ ni gbogbo igba pe awọn koni kọlu Ukraine bo tilẹ jẹ pe wọn ti ko ọmogun to le legberun lọna ọgọrun lọ si ibode Ukraine.

Olootu ijọba UK, Boris Johnson naa sọ pe asiko si wa fun Russia lati tun ero rẹ pa lori ọrọ Ukraine.

Johnson ni o dara ki ijiroro si maa lọ lori ọrọ naa lai duro.

Atẹjade kan sọ pe Ọgbẹni Johnson yoo sepade kan lọjọ Iṣẹgun lati jiroro lori igbesẹ UK lori ìbẹrù bojo to gbalẹ ni Ukraine.

Akọwe ijoba UK to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Liz Truss ni iwadii ti fihan pe Russia le ṣe ikọlu sí Ukraine.

Kinni Aarẹ Vladimir Putin sọ?

Aarẹ Putin beere lọwọ minisita ilẹ okeere rẹ, Sergei Lavrov bo ya o ṣeeṣe lati yanju ọrọ naa ni itubi inubi.

Ọgbẹni Lavrov ni o ṣeeṣe lati yanju ọrọ naa pẹlu ijiroro.

Amọ, awọn onwoye sọ pe ti ijiroro naa ko ba da lori ọrọ to wa nlẹ pe Ukraine fẹ darapọ mọ ajọ NATO, ọrọ naa ko le ni iyanju.

Kremlin ti sọ pe oun ko le gba ki Ukraine to jẹ ara Soviet Union tẹlẹ darapọ mọ ajọ NATO.

Ọpọ àwọn olóṣèlú ni wọn ti dé si ilu Moscow lori ọrọ naa.

Sugbon Russia duro lori ẹsẹ rẹ pe Ukraine ko gbọdọ darapọ mọ ajọ NATO.

Amọ, ajọ NATO ko fẹ gbọ si Russia lẹnu.