Dame Cressida: Inú ṣì ń bí mi torí àṣírí ìwà ìbàjẹ́ tó tú níléeṣẹ́ ọlọ́pàá kan lábẹ́ mi

Dame Cressida

Oríṣun àwòrán, Magnum Photos

Kọmisanna ọlọpaa agbegbe n'ilu London, Dame Cressida Dick, ti kọ̀wé fi ipo silẹ lẹhin ọpọlọpọ awuyewuye to n waye lori isẹ rẹ.

Dame Cressida sọ pe igbesẹ ọhun waye lẹyin ti olori ilu London, Sadiq Khan sọ fun oun pe ko ni igbagbọ ninu isakoso oun mọ.

Ọsẹ to kọja ni ajọ to n mojuto Ileeṣẹ ọlọpaa kede pe iwa ẹlẹyamẹya, idẹyẹsi, fifi oju tẹmbẹlu awọn obinrin, ati fifi ibalopọ lọni lọna aitọ, n waye laarin awọn ọlọpaa kan.

Dame Cressida to jẹ obinrin akọkọ to dari ileeṣẹ ọlọpaa to tobi julọ ni orile-ede United Kingdom, tun n koju èébú nitori iku arabinrin kan, Sarah Everard.

Ọlọpaa kan, Wayne Couzens, lo pa obinrin naa ni oṣù Kẹta, ọdun to kọja.

Dame Cressida Dick àti olootu ilu London, Sadiq Khan

Oríṣun àwòrán, EPA

Inu n bi mi nipa asiri iwa ibajẹ to tu nileesẹ ọlọpaa Charing Cross:

Wakati diẹ saaju ko to o fi ipo silẹ, Dame Cressida sọ fun BBC London pe, oun ko ni erongba lati fi iṣẹ silẹ, ati pe inu ṣi n bi oun si awọn iwa ibajẹ ti ajọ ọlọpaa tu aṣiri rẹ ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Charing Cross.

Ninu iwe to fi fi iṣẹ silẹ, o sọ pe oun ti gba lati duro fun asiko diẹ, ki nkan má ba a bajẹ, ki Kọmisanna ọlọpaa tuntun to o de.

Lara àwọn to ṣe e ṣe ko gba ipo rẹ ni awọn meji to jẹ igbakeji rẹ, Matt Jukes ati Neil Basu.

Yatọ si ilu London, ileeṣẹ ọlọpaa Met lo tun n gbogun ti igbesunmọmi jakejado orile-ede UK.

Olori ilu London, Sadiq Khan sọ pe inu oun ko dun si ọwọ ti Dame Cressida fi mu awọn ayipada to yẹ ko waye lori awọn iwa bii ẹlẹyamẹya, idunkookomọni, fifi oju tẹmbẹlu awọn obinrin ati fifi ibalopọ lọ wọn lọ́nà aitọ.

Ogoji ọdun ni Kọmisanna naa fi ṣe iṣẹ ọlọpaa.