Yomi Fabiyi: Mo ṣe sùúrù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó mi pẹ̀lú òyìnbò tó túka, kí ń tó bímọ mii ni

Yomi Fabiyi ati ọmọ tuntun

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi

Ayọ abara tín-in tín-in, ti ẹrin, ti ọyaya ni gbajugbaja òṣeré tiata nni, Yomi Fabiyi fi kede ọmọ tuntun jojolo ti Eledua fi ta a lọọrẹ.

Fabiyi sọ loju opo Instagram rẹ pe, idunnu ṣubu l'ayọ ni ọrọ ọmọ tuntun ti Ọlọrun fi jinki idile oun.

Ilúmọọka oṣere naa wa ki ọmọ ikoko naa kaabọ sí idile rẹ.

Yomi Fabiyi fesi si ahesọ ọrọ pe ko le bímọ:

Gbajugbaja oṣere Fabiyi ṣi aṣọ loju eegun ọrọ lori awọn to n sọ pe ko le bímọ fún BBC Yoruba.

Nigba to n ba BBC fọrọ werọ, Fabiyi ni ti ko ba nídìí, obinrin kii jẹ ikumolu ni ọrọ naa jẹ, bi bẹẹ kọ, oun ko ba ti gbe ọmọ tuntun jo ṣaaju akoko yii.

Fabiyi ni "awọn to n sọ pe n ko le bímọ ni aarun ọpọlọ lo jẹ kí wọn máa sọ bẹẹ.

Ti ori wọn ba pe ni, wọn ko ní joko sinu yara wọn, ki wọn sì maa sọ ohun ti oju wọn ko to lori ayelujara.

Ohun tó ṣẹlẹ ní pe mo ni lati ṣe suuru diẹ lẹyin ti igbeyawo ti mo ṣe pẹlu oyinbo tuka.

Igbeyawo kootu ni mo ṣe, o si nilo ki a ṣe suuru lati yanju ọrọ naa lẹyin ti a ko fẹ ara wa mọ.

Emi mọ ofin, ti n ko ba tii pari ipele kan, n ko le bọ sí omiran."

Yomi Fabiyi ati aya rẹ akọkọ to jẹ oyinbo

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Ọdun 2021 to kọjá lọ yii ni mo ṣẹṣẹ ri ọrọ igbeyawo mi to daru naa yanju:

Yomi Fabiyi ni ọdun to kọja lọ yii 2021, ni igbesẹ lati tuka pẹlu obinrin oyinbo ti oun fẹ tẹlẹ, sẹsẹ niyanju.

O fikun pe oun sẹsẹ ni anfaani bayi ni lati se igbeyawo pẹlu ẹlomiran, ki oun si ni idile tuntun.

"Mo sì tẹsiwaju pẹlu irin-ajo aye mi titi ti asiko Ọlọrun fi dé báyìí.

Isọkusọ lasan an l'awọn eeyan kan n sọ kiri lori ayelujara.

Amọ, ipakọ o gbọ suti ni ọrọ naa jẹ fún mi, ori ẹlẹgàn lo dari."

Àkọlé fídíò, Yomi Fabiyi ló ni ki òun àti ìyàwó rẹ̀ yàgò fún ra wọn

Mi o figba kankan ni idaduro lati bi ọmọ, mo ti bimọ tẹlẹ:

Gbajumọ osere naa ni ọpọ eeyan lo kan n gbe irọ kiri lori ayelujara lai ṣe iwadii ohun ti wọn n gbe kiri.

O ni iru awọn eeyan bẹẹ kan fẹ maa sọrọ ibajẹ lasan ni nipa oun lai mọ otitọ to wa nidi ọrọ naa.

"Kii ṣe ọmọ akọbi ti mo ma kọkọ bi ree, mo ti bímọ tẹlẹ rí.

Nitori naa, iwọfa lẹnu, ohun to ba wù ẹlẹnu lo lẹ fi ẹnu rẹ sọ.

Ẹbùn pàtàkì lati ọdọ Eledumare ni ọmọbibi.

Ọmọ tuntun kii ṣe ohun ti ẹnikẹni le fun wọn bi ẹbùn."

Ohun ti Yomi Fabiyi k soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

Nibo ni Yomi Fabiyi bímọ sí?

Ilumọọka oṣere, Fabiyi ti fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe orilẹ-ede Naijiria ni oun bímọ sí.

O ni ati oun ati iya ọmọ pẹlu ọmọ tuntun naa, Naijiria ni gbogbo awọn jọ wa.

Ọjọbọ ọjọ kẹwàá oṣu Kejì ọdun 2022 yii ni Eledua fi ọmọ naa ta idile oun lọrẹ.

Ta ni Yomi Fabiyi:

Gbajumọ osere tiata ni ede Yoruba ni Yomi Fabiyi, ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Karun si ni ọjọ ibi rẹ.

Ọ́mọ bibi ipinlẹ Ogun nii se amọ ilu Eko lo dagba si, to si ti lọ sile ẹkọ.

Oloogbe Babatunde Omidina, tii se Baba Suwe lo mu wọ agbo tiata, to si di ilumọọka nibẹ.

Obinrin oyinbo Fran, tii se ọmọ bibi ilẹ Gẹẹsi ni Yomi Fabiyi kọkọ fi se aya, ko to di pe igbeyawo naa daru lẹyin ọdun mẹsan.