Ukraine tensions:: Amẹrika ní orílẹ́èdè Russia lè kógun ja Ukraine nígbà kúùgbà

Oríṣun àwòrán, Reuters
Pẹlu irọkẹkẹ ogun to n gbode kan ni Ukraine bayii, ọpọ orilé-ede lo ti n kesi awọn eeyan wọn lati palẹ ara wọn mọ kuro nibẹ.Orílẹ̀-èdè méjìlá pàṣẹ̀ pé kí àwọn eèyàn wọn kúrò ní Ukraine nítorí ogun Russia tó súnmọ́ tòsí
Saaju ni arẹ ile America, Joe Biden ti kilọ fun Olori orilẹ-ede Russia, Vladmir Putin lori foonu lasiko ti wọn ti jọ n sọrọ.
Biden kilọ pe idojukọ si Ukraine yii ko ni jẹ igbesẹ to rọrun tabi to dara.
Aarẹ Ukraine ni tire, Volodymyr Zelensky sọ pe idunkooko ati ariwo ikọlu yii le mu ki awọn eeyan maa ko ọkan soke, ki wọn maa gbe ninu ipaya ati ohun to le mu ẹru dani.
- Kọmísánnà ọlọ́pàá ní London kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ torí ìkéde a kò nígbẹkẹ̀lé nínú rẹ mọ́
- Olubadan tuntun yóò di mímọ̀ lọ́jọ́ Ajé - Gómìnà Makinde
- Ìjọba Guinea-Bissau di ẹbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n rú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró
- Fásìtì yóò fí $250m gbára torí aṣemáṣe dókítà rẹ̀ pẹlu obìnrin
- Wo orílẹ̀èdè míì l‘Áfíríkà tí ìfipá gbàjọba tún ti ń rúgbó bọ̀
- Ọ̀rẹ́ ṣíṣe kò dé ìdí bọ́ọ̀lù, wo bí Mané ṣe gbomijé lójú Salah ní àṣekágbá AFCON 2021

Oríṣun àwòrán, EPA
Awọn mii wo lo ti kede ẹ pada sile fawọn eeyan wọn?
Orilẹ-ede America, Germany, ati United Kingdom ti ke si awọn eeyan wọn pe ki won maa pada bọ sile bayii.
Lọwọlọwọ ni Moscow ti ko ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ogun si aala aarin Ukraine ni eyi ti Russia si n tẹnumọ pe oun ko jagun.
Joe Biden ti ni ki awọn oṣiṣẹ ko pan dandan tete maa bọ sile kuro ni olu ilu Ukraine ni Kyiv.
Bakan naa ni Canada ti n ko awọn oṣiṣẹ rẹ lọ si Lviv to sunmọ aala Poland.
Russia funra rẹ naa ti kede pe oun n mu awọn eeyan oun lọ sibi to yẹ.
Australia, Italy, Isreal Netherlands, Japan naa ti kilọ fawọn eeyan wọn lati kuro ni Ukraine bayii.
Russia lè kógun ja Ukraine nígbà kúùgbà- Amẹrika kìlọ̀
Orilẹede Amẹrika ti kilọ pe nigba kugba ni Russia le kogun ja orilẹede Ukraine pẹlu bi nkan orilẹede ọhun ṣe n dunkoko mọ Ukraine lọwọ lọwọ.
Orilẹede Amẹrika ti wa sọ fun gbogbo ọmọ ilẹ Amẹrika to wa ni Ukraine lati kuro nibẹ ni kiakia.
Ileeṣẹ ijọba Amẹrika, White House sọ pe Russia le bẹrẹ ikọlu si Ukraine nipa yinyin ado oloro sinu ofurufu eleyii to la ṣakoba fawọn ọmọ Amẹrika lati kuro nigba naa.
- Ìjọba Guinea-Bissau di ẹbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n rú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró
- Wo orílẹ̀èdè míì l‘Áfíríkà tí ìfipá gbàjọba tún ti ń rúgbó bọ̀
- Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
- Mubarak, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ibadan lọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ikú rẹ̀ - àwọn ọ̀rẹ́ kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo
- Ilé alájà mẹ́ta dàwó ní Yaba nílùú Eko, àwọn èèyàn há sábẹ́ rẹ̀
Russia fesi si ọrọ Amẹrika lori ikọlu to le waye ni Ukraine
Ilu Moscow to jẹ olu ilu Russia ti sọ pe ko si ohun to jọ pe Russia fẹ ṣe ikọlu si Ukraine.
Ijọba Russia sọrọ yii bo tilẹ jẹ pe ọmogun Russia to le lẹgbẹrun lọna ọgọrun ni Russia ti ko lọ si ibode orilẹede Ukraine.
Ọrọ ti ilẹ Amẹrika sọ ti jẹ ki ọpọ orilẹede agbaye kilọ fawọn ọmọ ilu wọn to wa ni Ukraine lati wa lojufo.
Koda, ilẹ Amẹrika ti paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ rẹ kan to wa nile iṣẹ aṣoju ilẹ naa to wa ni ilu Kyiv pada si Amẹrika.
Aarẹ Joe Biden orilẹede Amẹrika ati Emmanuel Macron France ti fẹ ba Aarẹ Vladimir Putin ti Russia sọrọ lori foonu lori ọrọ to n lọ naa.
Amọ, Russia ti sọ pe awọn orilẹede bii Amẹrika atawọn orilẹede apa iwọ oorun ilẹ Yuroopu ni wọn n fi ẹwu da wahala silẹ ni Ukraine.
Orilẹede Amerika atawọn orilẹede ẹkun iwọ oorun Yuroopu n kọminu lori Russia
Orilẹede Amẹrika atawọn orilẹedee apa iwọ oorun Yuroopu ti kọminu lori bi Russia ti le ṣe ikọlu si Ukriane nigba kugba.
Ṣugbọn ominu to n kọ Amẹrika atawọn orilẹede Yuroopu ti pọ sii lẹnu ọjọ mẹta yii.
Amẹrika n kọminu pẹlu bi Russia ti n kawọn ọmogun lọ si ibode Ukraine atawọn ibi ti ko awọn ọmogun wọn si kaakiri.
Iwadii Amẹrika lo jẹ ki Aarẹ Biden sọ fawọn orilẹede mii to ti goke agba nilẹ Yuroopu pe afaimọ ki Aarẹ Putin ma paṣẹ ikọlu si Ukraine laipẹ.
Awọn ọmogun oju omi Russia ṣe igbaradi ni Crimea lọjọ Ẹti to kọja.
Bakan naa ni igbaradi ọlọjọ mẹwaa awọn ọmogun ni Belarus tẹsiwaju lapa ariwa Ukraine.
Ukraine gan an ti fẹsun kan Russia pe o dina mawọn lati le lo omi ọkun.
Ibẹru bojo to n lọ lọwọ yii waye lẹyin ti Russia ti wọ apa guusu Crimea peninsula fun ọdun mẹjọ bayii.
Lati igba naa ni awọn ọmogun Ukraine ti n koju awọn ọmogun ọlọtẹ ti Russia n ṣe atilẹyin fun.
Ileeṣẹ ọmogun Russia, the Kremlin sọ pe oun ko ni jẹ ki Ukraine darapọ mọ ajọ NATO.
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun lórí COVID-19, Ó mú àdínkù bá ìye èèyàn tó lè wọ ṣọ́ọ̀ṣì, mọ́sáláṣí
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000



















