AFCON 2021: Senegal tẹ Egypt mọ́lẹ̀ gba ife ẹ̀yẹ, wo ohun tó fàá tí Salah àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe já kulẹ̀ ní àṣeká gbá ìdíje

Awọn agbabọọlu Senegal n ṣe ajọyọ pẹlu ife ẹyẹ Afcon

Oríṣun àwòrán, cafonline.com

Sadio Mane, agbabọọlu Senegal lo gba bọọlu to sọ Senegal di ajagungbade idije ife ẹyẹ bọọlu Afrika, African Nations Cup lẹyin ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ọmi, ti wọn si fi pẹnariti yanju ọrọ naa pẹlu Egypt.

Agbabọọlu ikọ Liverpool naa ti kọkọ sọ pẹnariti to bọ sọwọ Senegal nu nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju keje, lẹyin ti wọn gbe agbabọọlu Egypt, Saliou Ciss ṣubu loju ile ikọ Egypt.

Amọ ṣa, aṣọle ikọ Paharaoh ti Egypt naa, Gabaski di eegun ẹja si Mane atawọn atamatase Senegal lọrun pẹlu bi o ṣe n mu gbogbo awọn bọọlu ti wọn n taari si ọdọ rẹ.

Igba akọkọ niyi ninu iwe itan Senegal ati ti idije naa, ti orilẹede ọhun yoo maa gba ife ẹyẹ odu awọn agbabọọlu orilẹede Afirika naa.

Ilana gbe e silẹ, ko gba a si goli, iyẹn pẹnariti ni wọn fi gbẹyẹ mọ Salah atawọn agbabọọlu akẹgbẹ rẹ lati Egypt lọwọ.

Salah, agbalu Egypt n waako lu agblu Senegal kan.

Oríṣun àwòrán, cafonline.com

Lai naani pẹnariti ti Mane sọnu, n ṣe lawọn agbabọọlu Senegal n ṣigun kọlu oju ile Egypt loorekoore, sibẹ ẹṣin wọn ko le e ta ni gbogbo bi ifẹsẹwọnsẹ naa ṣe n tẹsiwaju.

Lẹyin ọgọfa iṣẹju ti ikọ mejeeji yii fi woju ara wọn ni aṣekagba idije ife ẹyẹ bọọlu ilẹ Afirika naa, laisi ẹni to fi ajulọ han ara wọn ninu orilẹede mejeeji, lo mu ki alamojuto ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn rẹfiri, fọn fere pe ilana gbe e silẹ, ko gba a si goli, pẹnariti ni wọn yoo fi yanju rẹ.

Bona Sarr nikan lo gba tirẹ sọwọ goli lara awọn agbabọọlu Senegal, ti Abdel Meneam ati Mohana Ahmed lati ikọ Egypt pẹlu kuna lati gba tiwọn wọle.

Eyi lo mu ki Senegal bori idije naa pẹlu goolu mẹrin si meji.

Awọn koko manigbagbe nipa ifẹsẹwọnsẹ naa:

Awọn agbabọọlu Senegal n ṣe ajọyọ

Oríṣun àwòrán, cafonline.com

  • Igba karun niyi ti Egypty ati Senegal yoo maa fori-gbari ni idije ife ẹyẹ Afirika. Ọdun 2006 ni wọn pade ara wọn kẹyin nigba ti Egypt fi ajul han wọn ni ipele to kangun si aṣekagba pẹlu goolu meji si ẹyọ kan, 2-1.
  • Nigba mẹrin ti wọn koju ara wọn ṣaaju ti ọjọ Aiku, Egypt bori meji, Senegal pẹlu bori meji.
  • Aṣekagba kẹsan an niyi ti Egypt yoo maa gba ni idije ife ẹyẹ bọọlu Afirika, Ghana nikan lo tun ti farahan ni aṣekagba mẹsan bakan naa.
  • Igba kẹta niyi ti Senegal yoo maa wọ aṣekagba idije naa, wọn fidi rẹmi ni ọdun 2002 ati 2019.