Teenagers in Money Ritual: Àwọn ọ̀dọ́ tó fi ọ̀rẹ́bìnrin ṣe òògùn owó ní àwọn ṣa ní àdá lórí, fi ọ̀bẹ́ ge lọ́rùn sílẹ̀ ìṣẹ́ ibi tí wọn ṣe.

Awọn ọdọkunrin mẹrin to fi ọrẹbinrin se oogun owo

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police Command

Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ́n oṣù kìíní ọdún 2022 jẹ́ ọjọ́ tí àwọn olùgbé Oke-Aregba, Itoko-Tuntun, Idi-Ape àti Isoka ní Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun kò ní gbàgbé láéláé.

Ní ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rin, Soliu Majekodunmi; ẹni ọdun mejidinlogun, Wariz Oladehinde; ẹni ọdun mejidinlogun bakan naa ati Abdulgafar Lukman; ẹni ọdun mọkandinlogun.

Ẹni kẹrin ni Balogun Mustaqeem; ẹni ogun ọdun, tawọn mẹrẹẹrin si pawọ́pọ̀ ṣekúpa Sofiat Kehinde; ẹni ogun ọdun láti fi ṣe oògùn owó.

Nígbà tó ń jẹ́wọ́ fún àwọn ọlọ́pàá lórí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan an lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n pa Sofiat, Soliu ní lẹ́yìn tí òun ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní Mustaqeem fi àdá ṣá a lórí.

Ó ní Sofiat ké gbàjarè, tó sì dura nígbà tí àdá náà ba ní orí ṣùgbọ́n agbára rẹ̀ kò ká àwọn, títí tó fi jáde láyé.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Ó fi kun pé lẹ́yìn èyí ni àwọn gé orí rẹ̀, tí àwọn sì jo nínú ìkòkò nínú yàrá Soliu.

Wọn jẹwọ fun ọlọpaa pe miliki ni awọn yoo fi ma a lo ẹbu ti wọn ba ri lara ori naa, ki owo le de.

Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?

Ìwádìí fi hàn pé ariwo tí Sofiat pa kí ó tó kú, lo fu àwọn ará àdúgbò lára, tí wọn sì fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́dẹ létí.

Olórí àwọn ọlọ́dẹ Aregba àti agbègbè rẹ̀, Segun Adewusi ní nígbà tí àwọn ará àdúgbò fi tó àwọn létí wí pé ó jọ pé nǹkan aburú kan ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé náà, àwọn ya lọ ibẹ̀ ní bí aago mọ́kànlá alẹ́, tí ọwọ́ sì tẹ̀ àwọn mẹ́ta nínú wọn.

Adewusi ní nígbà tí àwọn wọ inú yàrá Mustaqeem làwọn bá orí tí wọ́n ń jó àti ara Sofiat tó kù, tí wọ́n dì sínú àpò.

Ó ní lẹ́sẹ̀ kan ni àwọn fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá Adatan létí tí wọ́n sì kó wọn lọ sí àgọ̀ ọlọ́pàá.

"Rofiat kìí ṣe ọmọ tó ní láárí, ó fẹ́ ọ̀rẹ́ méjì la ṣe ní ká fi ṣe òògùn owó"

Ọkan ninu awọn ọmọkunrin to fi ọmọbinrin kan ṣoogun owo nilu Abeokuta, ti jẹwọ pe ori ayelujara Facebook ni oun ti kọ nipa oogun owo.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abeokuta, Balogun Mustaqim to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun sọ pe ọsẹ meji ni awọn fi ṣe igbaradi fun fifi Rofiat Kehinde ṣe oogun owo.

O ni oun lo n kọkọ fẹ Rofiat ni ọdun 2021, ṣugbọn oun tun gba ki Soliu naa fẹ lẹyin ti awọn ko fẹ ara mọ.

O fikun pe nigba ti awọn dij n fẹ ara awọn, Rofiat kii se ọmọ to ni laari rara ni oun se fi silẹ nigba naa.

Kiakia naa si ni Sofiat naa gba lati fẹ Soliu.

Gẹgẹ bi nkan ti afurasi akọkọ, Mustakeem sọ, Soliu lo mu àbá wa pe ki wọn o fi ọmọbinrin naa ṣe oogun owo, lẹyin ọsẹ diẹ to bẹrẹ si ni fẹ.

O sọ pe oju opo Facebook kan ti wọn ti n sọ nipa "Aṣiri awọn oogun oṣolẹ (oogun owo) to daju ni oun ti kọ bi awọn yoo ṣe ṣe e.

Bi ọmọbinrin naa ṣe de ibẹ, wọn jọ ni ibalopọ.

Lẹyin naa lo pe Mustaqim wọle fun iṣẹ ibi ti wọn fẹẹ se.

Àkọlé fídíò, OLota

Níbo ni ẹjọ dé dúró lórí ọ̀rọ̀ náà?

Ile ẹjọ Majisireti kan nilu Abeokuta ti ju awọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin ti ọwọ tẹ lasiko ti wọn n fi ololufẹ ọkan lara wọn sẹ oogun owo si ọgba ẹwọn.

Ẹsun igbimọpọ ati ipaniyan ni wọn fi kan wọn.

Onidajọ I.O Abudu paṣẹ pe ki wọn o ju wọn si ọgba ẹwọn to wa ni Oba titi ti ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Ogun yoo fi sọ igbesẹ to kan lori ọrọ wọn.

O si sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta.

Ṣe lootọ ni oogun owo wa?

Babalawo kan ti BBC Yoruba ba sọrọ, Olukunle Idowu, sọ pe ko si nkan to n jẹ etutu ọla tabi oogun owo ninu Ifa.

O ni to ba jẹ pe o wa ni, oun paapaa yoo ti ni owo tabua lọwọ.

Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan pe awọn babalawo lo n ṣe oogun ọrọ fawọn ọdọmọde ti wọn n wa owo ojiji lasiko yii.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin fifi awọn eeyan ṣe oogun ti wa wọ pọ lawujọ.

Babalawo Idowu sọ pe ikanju lo bi gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lati inu ile bọ si ode to fi de ọdọ ijọba.

Àkọlé fídíò, Jejere