Queen Elizabeth: Ọbabinrin ní láti inú ọkàn òun ni òun ti fẹ́ kí Camilaa di ayaba

Camilla ati Ọbabinrin Elizabeth

Oríṣun àwòrán, Danny Lawson

Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Elizabeth ti kede pe ki wọn fi Camilla aya Ọmọọba Charles jẹ ayaba nigba ti ọkọ rẹ ba jọba lẹyin oun.

Ninu ọrọ to fi ransẹ lati sami ajọdun aadọrin ọdun to ti gun ori itẹ, Ọbabinrin ni lati inu ọkan oun lo ti wa pe ki Camilla di ẹni ti yoo jẹ oye.

Bi o tilẹ jẹ pe ọrọ kan ti n ja rainrain nilẹ tẹlẹ pe o seesee ko jẹ pe aya ọmọọba Charles naa ni yoo jẹ ayaba amọ ikede Ọbabinrin Elizabeth yii lo wa fi ontẹ lu igbesẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Isẹ ti Queen fi ransẹ naa si lo yanju ibeere to ti n ja rainrain lọkan awọn eeyan tẹlẹ pe ta ni yoo jẹ oye ayaba lọjọ iwaju.

Agbẹnusọ kan fun idile ọba ni ọmọba Charles ati aya rẹ, Camilla ni wọn ri ikede naa bii ọla nla, to si dun mọ wọn ninu.

Ki ni pataki oye yii ?

Oye 'Queen Consort' yii ni wọn maa fi n pe aya ọba to ba wa ni ori oye, eyi si tumọ si pe ayaba Camilla ni yoo jẹ oye naa lọjọ iwaju.

To ba jẹ pe bo se maa n waye tẹlẹ ni, Camilla lo jẹ ko jẹ ayaba ni kete ti ọkọ rẹ, Charles ba gun ori itẹ.

Amọ ẹnu to n kun Camilla lati ọdọ awọn araalu ni lo tọkasi pe eyi le ma ri bẹẹ ti Ọbabinrin ba waja.

Àkọlé fídíò, Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Ki lo sẹlẹ sẹyin?

Ọmọọba Charles ati Camilla lo ti sẹ igbeyawo ọtọọtọ pẹlu obinrin miran ati ọkunrin miran tẹlẹ, ki wọn tun to pada ba ara wọn se igbeyawo lọdun 2005.

Amọ igbeyawo naa ni wọn ko se ni ti alarinrin eyi ti wọn maa n se fun awọn idile ọla.

Charles lo ti se ugbeyawo tẹlẹ pẹlu Ọmọọbabinrin Diana amọ ti wọn kọ ara wọn silẹ lọdun 1996,ko to di pe Diana ni ijamba ọkọ nilu Paris lẹyin ọdun kan, to si ku.

Nigba ti Camilla wa se igbeyawo pẹlu Charles, ero araalu ni pe Ọmọọbabinrin lasan ni oye ti wọn yoo fun amọ bi ọdun se n yi gun ori ọdun, ni erongba lati fun ni oye nla n fi oju han.

Ikede Ọbabinrin Elizabeth yii si lo mu isoro ti Camilla le ni kuro lati di ayaba, ti yoo si maa se awọn ojuse to jẹ ti ayaba ti ọkọ rẹ ba gun ori itẹ.