Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ Agbekoya ṣèlèrí láti tú Sunday Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n pẹ̀lú agbára Yorùbá

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Instagram/Sunday Igboho

Ẹgbẹ Agbekoya ti sọ pe awọn ṣetan lati lo agbara awọn agba lati tu Oloye Sunday Igboho silẹ ni atimọle to wa lorilẹede Benin Republic.

Ẹgbẹ Agbekoya igbesẹ yii ṣe pataki lẹyin ti ijọba Benin Republic lati fun un ni ominira.

Ni ilu Osogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Osun ni ọrọ yii ti jade nibi ti ẹgbẹ naa ti ṣe iwọde lati fi aidunnu wọn han lori bi nkan ṣe ri niluu.

Agbekoya sọ erongba wọn lori atimọle Sunday Igboho

Aarẹ ẹgbẹ Agbekoya, Oloye Kamorudeen Okikiola sọrọ o fa kumookun rẹ yọ nibi ifẹhonuhan to waye niluu Osogbo.

Oloye Okikiola ni ''Sunday Igboho kii ṣe ọdaran, ajijagbaominira ni i ṣe.

Àkọlé fídíò, Jejere

Ọna aitọ ni wọn fi ti i mọle ni Benin Republic, ijọba Naijiria lo si wa nidi ọrọ yii.

Ijọba ti dẹkun gbigbe e lọ sile ẹjọ, idi niyii ti a fi n sọ fun ijọba lati tu u silẹ lẹwọn to wa.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Ṣugbọn ti wọn ba kọ lati fun un ni ominira, awa ẹgbẹ Agbekoya yoo lo agbara awọn agba lati yọ Igboho ninu ọfin to wa.

Mo tun sọ lẹkan sii pe Agbekoya yoo yọ Igboho Ooṣa kuro ninu ọgba ẹwọn to wa ni Benin Republic ti wọn ba kọ lati fi i silẹ.

Àkọlé fídíò, OLota

Agbekoya koro oju si eto abo to mẹhẹ ni Naijiria

Ẹgbẹ Agbekoya tun lo ifẹhonuhan ọhun lati fi aidunnu wọn han lori eto abo to mẹhẹ kaakiri Naijiria.

Wọn pe fun atunto orilẹede Naijiria ati atunṣe iwe ofin ọdun 1999 ṣaaju ibo gbogbogbo ọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Ẹgbẹ Agbekoya ni Naijiria ko le lọ siwaju lai ṣe awọn atunṣe wọnyii.

''Niṣe lo yẹ ki pada si iwe ofin Naijiria ọdun 1960 eleyii ti a fi gba ominira.

Iwe ofin yii lo fun ẹkun kọọkan lagbara mojuto awọn eeyan rẹ daadaa lai nan ni ẹni to wa ni ipo aarẹ.

Idi niyii ti atunto Naijiria fi ṣe pataki ki a to tun dibo mii lọdun 2023.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọrọ lori ohun tawọn gomina ilẹ Yoruba n ṣe lori bi wọn ju Oloye Sunday Adeyemo(Igboho) si atimọle ni ilu Cotonou, lorilẹede Benin.

Ọpọ eeyan lo ti n kọminu pe awọn gomina apa iwọ oorun guusu ko sọ ohun kan loi bi wọn ṣe mu Igboho lorilẹede Benin.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Gomina Sanwo-Olu sọ fawọn akọroyin nibi eto idibo ijọba ibilẹ Eko lọjọ Abamẹta pe iṣẹ n lọ labẹlẹ lori ọrọ Igboho.

''Awọn eeyan n ṣiṣẹ lọ labẹlẹ, ko digba tawọn gomina ba to n sọrọ ni gbangba ki araalu to mọ pe wọn o dakẹ lori ọrọ Igboho.

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Asiko yii to le ni akoko yii fun gbogbo wa, ṣugbọn mo fẹ fi da yin loju pe iṣẹ n lọ labẹlẹ.

Nibi ti ọrọ de duro bayii, ko niṣe pẹlu iye awọn akọroyin ti eeyan ba ba sọrọ.

Ohun ti mo mọ ni pe ọpọ eeyan lo n ṣiṣẹ lẹgbẹ lẹgbẹ ati lọlọdanni, ko digba ti wọn ba to sọrọ ni gbangba,'' Sanwo-Olu ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ọjọ Aje ọjọ kọkandinlogun oṣu keje lawọn agbofinro mu Igboho ni papakọ ofurufu Cadjèhoun niluu Cotonou, lorilẹede Benin.

Oun ati iyawo rẹ, Ropo ni wọn n jọ n rinrin ajo lọ si orilẹede Germany nibi ti wọn ti fẹ wọ baalu laago mẹjọ alẹ ki wọn to mu wọn.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Ṣugbọn awọn gomina ilẹ Yoruba ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lati ọjọ Aje ti Igboho ti wa ni gbaga ọlọpaa.

Ohun ti ijọba orilẹede Naijiria sọ fun Benin ni pe Igboho ti lu ofin ni Naijiria wi pe ki wọn mu un nibẹ.

Àkọlé fídíò, Reminisce: Àwọn ọ̀dọ́ ló mọ ìtumọ̀ orin 'Problem'

Awọn aṣoju ijọba Naijiria tun sọ fun ile ẹjọ ni Benin pe Igboho ko ibọn pamọ sile eleyii ti o fẹ lo lati pin orilẹede Naijiria.

Wọn tun sọ pe Igboho n lo awọn eeyan lati da ilu ru.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Ijọba Naijiria tun sọ pe Igboho n ṣe fayawọ ibọn.

Ṣugbọn ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho, Ibrahim Salami to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ko si otitọ kankan ninu awọn naa.