Nigeria population: Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe agbekalẹ eto ti yoo ṣe adinku ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ lorilẹede Naijiria.

Buhari to ṣe agbekalẹ eto naa niluu Abuja sọ pe o ṣe pataki bayii lati mu ifeto sọmọ bibi lọkunkundun.

Buhari tun ṣe agbekalẹ eto mii ti yoo ṣe iranwọ lori ati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n pọ sii ni Naijiria.

Buhari ṣe agbekalẹ eto ifeto sọmọ bibi

Aarẹ Buhari ṣalaye pe ohun to bi eto ifeto sọmọ bibi wa ni lati mu ibayegbadun ba awọn ọmọ Naijiria.

Buhari ni eyi wa lara awọn eto ijọba ẹgbẹ oṣelu APC to wa lode bayii.

Àkọlé fídíò, Jejere

Eto yii yoo ṣe iranwọ lori bi adinku yoo ṣe ba bi ọpọ eeyan ṣe n bi ọmọ silẹ lọpọ yanturu.

Ara awọn ọna ti ijọba fẹ gba lati ṣe eto ọhun ni nipa ilanilọyẹ lori ifeto sọmọ bibi.

Aarẹ Buhari gbagbọ pe eto yii yoo ran ọpọ eeyan lọwọ lati fi alafao si aarin awọn ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Buhari kọminu lori bi Naijiria ṣe pọ julọ l'Afrika

Aarẹ Buhari ni orilẹede naijiria lo pọ julọ nilẹ Afirika nigba to tun jẹ orilẹede to wa ni ipo keje lagbaye.

Buhari ni Naijiria wa lara awọn orilẹede diẹ lagbaaye to ni ọdọ julọ.

Àkọlé fídíò, OLota

Aarẹ ni ida mejilelaadọrin ninu ọgọrun awọn ọdọ yii ni ọjọ ori wọn ko to ọgbọn ọdun.

Bakan naa ni Buhari sọ pe idaji awọn obinrin ninu awọn ọdọ yii lo wa ni asiko ti wọn ṣe abiamọ tori ọjọ ori bẹrẹ lati ọdun mẹẹdogun si ọdun mọkadinlaadọta.

Ọna abayọ si ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ

Buhari ni ijọba ko ni dẹkun lilo eto ẹkọ to peye lati maa la awọn eeyan lọyẹ.

Aarẹ ni eto ẹkọ yoo ṣe iranwọ papaa julọ fawọn obinrin to ba jẹ ọmọde tori awọn ni wọn le gboyun nigba kugba.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Buhari tun sọ pe eto ikaniyan to n bọ yoo tun ṣe iranwọ lati mọ ọna lati mu adinku ba ọmọ bẹẹrẹ oṣi bẹẹrẹ.

Ni bayii, akọsilẹ fihan pe eeyan to wa ni Naijiria le ni ẹgbẹrun lọna igba eleyii yoo si tun pọ sii lọjọ iwaju.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi