Shina Peller: Ọ̀gá àgbà NSCDC dá àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ náà tó wà pẹ̀lú Shina Peller padà

Oríṣun àwòrán, Shia Peller
Ọga agba ẹṣọ ara ẹni laabo ilu, NSCDC, Ọmọwe Ahmed Abubakar Audi ti paṣẹ idapada awọn ẹṣọ NSCDC to n ṣiṣẹ pẹlu aṣoju-ṣofin l'Abuja, Shina Peller.
Iroyin kọkọ jade ni Ọjọru pe ajọ naa ti paṣẹ pe kawọn ẹṣọ NSCDC to n ṣiṣẹ pẹlu Peller fi i silẹ tori da aba wi pe ki ijọba wọgile ajọ naa ko si dawọn pọ awọn ọlọpaa.
Ẹkun lseyin/ltesiwaju/ Kajola/lwajowa nipinlẹ Oyo ni Peller n ṣoju fun nile igbimọ aṣofin niluu Abuja.
- A kò fi ẹbí Timothy sílẹ̀, à ń gbiyànjú pé kí wọ́n dá ẹjọ́ náà padà sí Osun dípò Abuja ni- Agbẹjọ́rò Adekilekun
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Ramon Adedoyin t'ọ́lọ́pàá mú nítorí ikú Timothy Adegoke gba ilé ẹjọ́ lọ, ohun tílé ẹjọ́ sọ rèé...
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
- Ẹ̀jọ́ àtí ìwádìí ikú Timothy Adegoke ti kúró lọ́dọ̀ọ wa nípinlẹ̀ Osun- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Oṣun
- Ìyàwó Timothy Adedoge ké gbàjarè lórí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa ọkọ rẹ̀
- Kí ló ń dá ọlọ́pàá dúró láti gbé Rahmon Adedoyin àti ọmọ rẹ̀ relé ẹjọ́ lórí ikú Timothy Adegoke?
- Ṣé Odunlade Adekola àti Toyin Abraham kò ṣe 'Ambassador' rógo báyìí?
Kinni Shina Peller sọ gan an nile aṣoju-ṣofin l'Abuja?
Aṣofin Peller da aba pe ki ijọba da ajọ NDCDC pọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa.
Ile aṣofin si gba aba naa wọle fun ipele akọkọ ni ọjọ Iṣẹgun ti wọn jiroro lori rẹ.
Peller ṣalaye nigba to n gbe aba ọhun silẹ pe ki ijọba gbe igbimọ kan ti yoo ṣiṣẹ lori ati da awọn oṣiṣẹ NSCDC pọ mọ awọn ọlọpaa
Bakan naa lo tun sọ pe ki ijọba gbe igbimọ mii dide ti yoo ṣe amojuto bi wọn ti maa da awọn irinṣẹ ajọ NSCDC pọ mọ tawọn ọlọpaa.
Ọga agba ajọ NSCDC paṣẹ pe kawọn ẹṣọ ajọ naa Shina Peller silẹ
Ọga agba ẹṣọ ara ẹni laabo ilu, NSCDC, Ọmọwe Ahmed Abubakar Audi paṣẹ lẹyin ti aṣofin Peller da aba ọhun tan pe kawọn ẹṣọ NSCDC fi i silẹ.
A gbọ pe aṣẹ naa wa ninu iwe kan ti ajọ NSCDC kọ si aṣofin Peller lọjọ Iṣẹgun.
Wọn kọ sinu iwe naa pe awọn ẹṣọ to wa pẹlu rẹ ni lati kuro ni kiakia nitori iṣẹ pajawiri kan to suyọ.
Ajọ naa tọrọ aforijin lori inira ti igbesẹ naa le fa fun un.
- Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀
- Àwọn ọlọ́pàá méjì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
Ọga agba ajọ NSCDC paṣẹ idapada awọn ẹṣọ Shina Peller
Lẹyin ọ rẹyin, ọga agba NSCDC naa lo paṣẹ pe kawọn ẹṣọ ajọ naa to fi Peller silẹ pada sọdọ rẹ.
Ni aarọ Ọjọru ni ọga agba NSCDC pa idi ọrẹ da ti o si paṣẹ pe kawọn ẹṣọ naa pada.
Agbẹnusọ ajọ NSCDC, Odumosu Olusola, lo buwọlu atẹjade ti ajọ naa fi da awọn ẹṣọ NSCDC pada sọdọ Peller.

















