Maiduguri IGP son wedding: Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba

Alejo nibi igbeyawo ni Maiduguri

Oríṣun àwòrán, Others

Bi o ṣe n ṣepo, ko ṣọra.

Ohun to kọ iwaju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si elomii ni ọrọ awọn ero to wa sibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ ọga agba awọn agbofinro ni Naijiria to waye ni ana, ọjọ Satide, ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2022 ni Maiduguri ni ipinlẹ Bornu.

Ana ode yii ni Maina Alkali to jẹ ọmọkunrin Baba Alkali to jẹ ọga agba pata fun gbogbo awọn ọlọpaa ni Naijiria ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ ni Maiduguri.

Aafin Shehu ti borno, Abubakar El-Kanemi ni Maiduguri ni eto igbeyawo naa ti waye ni olu ilu Bornu ni ariwa Naijiria.

Awon wo lo wa sibi igbeyawo naa?

Ọpọlopọ gbajumọ lo peju sibi eto igbeyawo naa ni ipinle Bornu.

Die lara wọn ni Abba Kyari to jẹ olori ikọ ọtẹlẹmuyẹ idahun pajawiri ti ẹnu n kun lati ọdun to kọja pe o gba abẹtẹlẹ to pọ to si di wahalaKí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?

Àkọlé fídíò, Ijinigbe: BBC ṣe ìwádìí bí ikọ̀ IRT ṣe ń gbéjà ko awọn ajinigbe lójú

Awọn mii to tun wa nibi igbeyawo naa ni: Obinna Iyiegbu ti ọpọ mọ si Obi Cubana to di gbajugbaja sii lẹyin to sinku iya rẹ pẹlu ọpọlọpọ maalu to n jẹ ki araye kigbe kiri Wo ǹkan mẹ́ẹ̀dògún tó yẹ kí o mọ̀ nípa olówó ayé Obi Cubana

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum naa wa lara awọn to peju peṣẹ sibẹ.

Gomina ipinlẹ Yobe ati Jigawa, Mai Mala Buni ati Badaru Abubakar naa ba wọn peju yọ ayọ igbeyawo ọmọ Baba Alkali naa.

igbeyawo Maiduguri

Oríṣun àwòrán, @Abba Kyari facebook

Kini o bi ẹjọ lori ayelujara lori igbeyawo ọmọ ọga ọlọpaa naa?

Ni kete ti awọn ọmọ Naijiria ti n ri aworan pe abba Kyari to n koju ẹsun riba gbigba naa wa nibé ni awọn ọmọ Naijiria ti n sọrọ lori ayelujara.

Ko pẹ si asiko igbeyawo yii naa ni Abba Kyari si ko fọto to pọ soju opo facebook rẹ ni eyi ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni sọ di koko ijiroro lori ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n ni ko buru ni awọn míì ní ko yẹ ko ri bẹẹ.

igbeyawo Maiduguri

Oríṣun àwòrán, others

Awon mii to tun wa nibi igbeyawo Alkali naa ni Aarẹ awon Asofin ni Abuja, Ahmad Lawan, Minista fun iriina oju ofurufu, iyẹn Hadi Sirika, Aliko Dangote to jẹ olowo oniṣowo ilẹ Adulawo ati Aminu Ahmed, oludari ileeṣẹ Tiamin.

igbeyawo Maiduguri

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn orukọ wo ni wọn n sọ nipa wọn?

Ni kete ti Abba Kyari ati awọn mii ti ṣafihan awọn aworan ti wọn ya nibi eto igbeyawo ọmọ Alkali Baba naa ni awọn eeyan ti n sọrọ lori ayelujara ti orukọ awọn mii si ti n jade.

Orukọ bii Igbalode Ramoni ti ọpọ mọ si Hushpuppi ti o fẹsun kan Abba Kyari naa ti n jade pẹlu.

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Hushpuppi lo n jẹ ẹjọ lọwọ ni orilẹ-ede America lẹyin ti United States of America's Federal Bureau of Investigation fẹsun kan an.

Bakan naa ni orukọ Obi Cubana naa tun n jade pelu irufẹ eto isinku alarinrin to ṣe fun iya rẹ seyin.