US East Coast: Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle

Oríṣun àwòrán, Reuters
Nkan ti n dẹnukọlẹ ni Ila oorun orilẹ-ede America, nitori fun igba akọkọ lọdun mẹrin.
Awọn awoye oju ọjọ sọ pe iji lile naa yoo lọ lati Carolinas si Maine, pẹlu ilẹ mimi ni awọn agbegbe to wa leti omi.
Ipinlẹ marun-un nilẹ America lo ti kede nkan o fararọ pẹlu ikilọ pe ki awọn olugbe ibẹ ma jade si ojupopo rara fun aabo ara wọn.
Awọn ipinlẹ naa ni New York, New Jersey, Maryland, Rhode Island ati Virginia.
Bakan naa ni awọn awoye kilọ pe o ṣe e ṣe ki omiyale o waye ni awọn agbegbe to wa ni eti omi.
Irinajo baalu to le ni ẹgbẹrun marun-un ni wọn wọgile laarin ọjọ Ẹti si ọjọ Aiku, gẹgẹ bi akọsilẹ FlightAware.
- Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC ṣe ìfilọ́lẹ̀ àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor
- Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó ní Buhari ti kú, Jubril Sudan ló ń darí Nàíjíríà
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
- Ìjọba Tanzania yòó fi òfin gbé òbí tí ọmọ rẹ̀ bá sá níé ẹ̀kọ́
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
Awọn onimọ sọ pe lasiko iji lile naa, afẹfẹ tutu nireti wa pe yoo dapọ mọ ooru to n jade ninu òkun. Eyi yoo mu ki ayipada oju ọjọ ranpẹ o waye.
Eyi pọju olodinwọn aadọrin sẹntimita to ṣẹlẹ lọdun 2003.
Yatọ si eyi, wọn ni o ṣeeṣe ki iji lile naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Nor'easter bo agbegbe Boston mọlẹ patapata pẹlu yìnyín tó ga to ẹsẹ bata meji.
Nitori naa si ni ajọ to n mojuto ayipada oju ọjọ ni Boston sọ pe irinajo pajawiri nikan ni ki awọn alaṣẹ fi aaye gba lasiko yii.
Owurọ ọjọ Abamẹta ni ọwọ iji lile naa bẹrẹ si ni kan awọn eti omi nilẹ America, ti yìnyín si ti n jabọ ni ọpọlọpọ ipinlẹ.
Eniyan bi miliọnu marundinlọgọrin si lo wa ni awọn ibi ti iji na yoo ti jà.















