BBC Komla Dumor Award 2022: Iléeṣẹ́ ìròyìn BBC ṣe ìfilọ́lẹ̀ àmì ẹ̀yẹ Komla Dumor

Komla Dumor

Ileeṣẹ iroyin BBC n wa awọn akọroyin to jẹ ọdọ to tun dantọ lati gba ami ẹyẹ "BBC World News Komla Dumor Award," ti ọdun 2022.

BBC wa n ke si awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọ silẹ fun ami ẹyẹ naa, pẹlu erongba lati ṣawari awọn akọroyin to dantọ nilẹ Afrika.

Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa yoo lo oṣu mẹta ni olu ileeṣẹ iroyin BBC to wa niluu London, nibi ti yoo ti kọ si nipa iṣẹ akọroyin.

Aago mejila oru, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keji, ọdun 2022 ni eto iforukọsilẹ naa yoo wa sopin.

Wọn ṣe agbekalẹ ami ẹyẹ nyii i iranti akọrọroyin BBC ọmọ orilẹ-ede Ghana kan to lamilaaka, fun iṣẹ ribiribi to ṣe gẹgẹ bii akóroyin BBC ko to dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelogoji lọdun 2014.

Iyawo rẹ, Kwansema Dumor sọ fun ẹni to ti gba ami ẹyẹ naa kẹyin, Victoria Rubadiri pe inu oun dun fun ipa ti oloogbe naa ni nileeṣẹ iroyin BBC, ati bi wọn ṣe n ṣe iranti rẹ nipa ami ẹyẹ ọhun.

BBC ti wa rọ awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọsilẹ fun anfani lati gba ami ẹyẹ ọhun, eyii ti yoo ṣe ayẹsi awọn akọroyin ni Afrika.

V Rubadiri
This opportunity gave me a continental perspective of the news market and opened my mind to new ways of telling the African story"
Victoria Rubadiri
BBC World News Komla Dumor Award winner 2020
1px transparent line

Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa, yatọ si pe yoo gba idanilẹkọọ nileeṣẹ iroyin BBC ni London, yoo tun ni anfaani lati rinrinajo lọ silẹ Afrika kan lati jabọ iroyin to ba nifẹ si, eyii ti a oo ṣafihan rẹ fun gbogbo agbaye.

Nigba aye rẹ, ipa ti Dumor ko nileeṣẹ iroyin BBC ko kere, BBC si n fi ami ẹyẹ naa ṣe iranti rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Rubadiri ko le ṣe idanilẹkọọ naa lọdun 2020, wọn sun idanilẹkọọ ọhun si 2021.

Lasiko idanilẹkọọ rẹ, o rinriajo lọ si ilu Kinshasa, tii ṣe olu ilu orilẹ-ede Democratic Republic of Congo lati jabọ iroyin nipa aapu to ni ṣe pẹlu irinajo oju popo.

Ọga agba BBC, Tim Davies lo si gbe ami ẹyẹ naa le lọwọ.

Ta ni Komla Dumor?

Dumor darapọ mọ BBC lọdun 2007 lẹyin to ti kọkọ ṣiṣe lawọn ileeṣẹ iroyin kan ni Ghana, tii ṣe orilẹ-ede rẹ.

Laarin ọdun 2007 si 2009, oun lo maa n tukọ eto Network Africa fun ẹka "BBC World Service", nigba to kuro nibẹ o darapọ mọ eto "The World Today."

Ni 2009, Dumor ni ẹni akọkọ ti yoo tukọ eto "African Business" lori ikanni BBC World News ati Africa Business report.

O rinrinajo kaakiri ilẹ Afrika, nibi to ti ba awọn alẹnulọrọ nipa owo ṣiṣẹ kaakiri ilẹ Afrika pade.

Lọdun 2013, iwe iroyin New African magazine kede rẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ ilẹ Afrika ọgọrun to lẹnu julọ.

Presentational grey line

Awọ to ti gba ami ẹyẹ naa sẹyin?:

  • 2015: Nancy Kacungira latiUganda
  • 2016: Didi Akinyelure lati Nigeria
  • 2017: Amina Yuguda lati Nigeria
  • 2018: Waihiga Mwaura lati Kenya
  • 2019: Solomon Serwanjja lati Uganda
  • 2020: Victoria Rubadiri lati Kenya
Presentational grey line