Obi Cubana: Ilé ijó 'Hustle and Bustle' di tìtì pa lẹ́yìn ikú olùgbafẹ́ kan

Obi cubana

Oríṣun àwòrán, Instagram/obi cubana

Ile ijo Hustle and Bustle to jẹ ti gbajugbaja oniṣowo un ni, Obinna Iyiegbu ti ọpọ mọ si Obi Cubana ti di titi pa.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn alaṣẹ ile ijo naa kede pe ibi igbafẹ ọhun tipa di ọjọ mii ọjọ 're lẹyin ti ina gbe olùgbafẹ́ kan lọjọ Aiku ti o si gba ibẹ dero ọrun.

Ninu atẹjade kan ti ile ijo ọhún fi sita, wọn ṣalaye pe awọn ti ile ijo naa tipa tori onibaara wọn kan to ku lai ro tẹlẹ.

Wọn ni ọgbẹ ọkàn ni iṣẹlẹ naa jẹ eleyii ti awọn nilo asiko diẹ lati mu ọkan awọn le lori iṣẹlẹ naa.

Iwadii ti BBC ṣe fihan pe obinrin ni ẹni to ku naa ṣugbọn BBC ko mọ bi iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn alaṣẹ ile ijo gbadura pe kí Eledua tun awọn ẹbi oloogbe naa ninu.

Ohun tí BBC mọ nipa iṣẹlẹ naa ree

iwe atẹjade naa

Oríṣun àwòrán, Instagram

Awọn ẹṣọ ile ijo niluu Abuja sọ fun BBC pe ile ijo ọhún ti wa ni titi pa lootọọ.

Amọ, awọn ẹṣọ naa ko ṣalaye ni kikun ohun to ṣẹlẹ gan an.

Ile ijo Hustle and Bustle wa ni agbegbe Wuse 2 ni nọmba 80, Aminu Kanu Crescent.

Ile ijo Hustle and Bustle jẹ ọkan lara awọn okoowo Obi Cubana.