Ọ̀nà wo la lè gbà dáàbò bo àwọn olùkọ́ lọ́wọ́ kọ̀lọ̀rànsí akẹ́kọ̀ọ́ tó ń lù wọ́n níléẹ̀kọ́?

Students for class
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Isọwọ bi awọn akẹkọọ ti ṣe n da bantẹ iya fawọn olukọ wọn lẹnu ọjọ melo kan yii jẹ nkan to n kọ ọpọ lominu ni Naijiria.

Yala ni ileẹkọ girama ni tabi lawọn to wa ni fasiti niṣe ni iwa yi n peleke sii tawọn oluwoye si n ke gbajare pe ki awọn alẹnulọrọ wa nkan ṣe sii.

Laipẹ yi ni akẹkọọ fasiti Ilorin kan lọ ka olukọ rẹ mọ inu ọfisi to si lu laludaku.

Ṣaaju asiko yi a tun gbọ pe inu ibẹrubojo lawọn olukọ ileẹkọ girama kan wa ni ipinlẹ Ogun nitori bawọn akẹkọọ kan ṣe sọọ di aṣa tuntun lati maa doju ija ka olukọ wọn.

Lootọ iru awọn iṣẹlẹ bayile ti waye nigba kan ri ṣugbọn igi gogoro ma gun mi loju, at'okere la ti n wo o ni Yoruba maa n wi, eyi lo mu ki BBC Yoruba tete maa wo o lati okere.

Ileeṣẹ iroyin BBC ba akọsẹmọṣẹ onimọ nipa ọrọ ọpọlọ kan lati fasiti ilu Eko sọrọ to si ṣalaye ohun to le fa iru iwa yi laarin awọn akẹkọọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya

Ọjọgbọn Olurotimi Coker sọ pe awọn nkan to le ṣokunfa iru wa yi pọ.

O ni eleyi to lewaju ninu rẹ ni pe pupọ awọn akẹkọọ fasiti ati ile ẹkọ a lode oni ti n yara dagba ti pupọ a si maa dabi agbalagba ni oju ati ni ihuwasi.

Onimọ yi sọ pe bi eeyan ko ba dagba de aaye kan, kole ṣaadede sọ pe ohun yoo lu olukọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Wo òkè ìṣẹ̀mbáyé Abanijorin yìí l'Ekiti tó máa ń bá ọ̀kọ̀ rìn lójú pópó tó tún ní ilé ìwòran orí ìtàgé nínú rẹ̀

'''Bi ẹ ba ri awọn akẹkọọ to wa ni ile ẹkọ girama tabi fasiti lode oni, niṣe ni wọn da bi agbalagba loju. Ọpọ lo ti n gbe irin ti wọn si ti ni iṣu lapa bii ẹni to n ja ẹṣẹ.''

Ọjọgbọn Olurotimi ni nitori pe wọn ri gidigba loju wọn a maa foju wo awọn olukọ to ba kere si wọn ti wọn a si maa ro pe o yẹ ki ipa awọn ka iru ẹni bẹẹ.

''Ti a ba mu bi wọn ti ṣe ri gidigba yii ta wa fi lilo awọn oogun oloro pẹlu rẹ, eleyi a maa mu ki wọn gboya lati koju awọn alaṣẹ lai bikita rara''.

e awọn olukọ lẹ́bi ninu ọrọ yii?

Ọjọgbọn yi ni awọn olukọ ni lati kọ ẹkọ sii nipa bi wọn yoo ṣe maa ba awọn akẹkọ́ọ sọrọ.

O ni idi ni pe pupọ awọn akẹkọọ yi lo ti di agbalagba ti wọn si gbọdọ maa fi ọgbọn ati oye ba wọn sọrọ.

''Awọn olukọ tawọn akẹkọọ yi n doju ija kọ lawọn ti wọn ro pe wọn kii gba gbẹrẹ rara. Bi wọn ba ti foju wo olukọ pe o buru iru awọn eeyan bayi ni wọn maa n ba ja''.

O ni lati koju iru iṣẹlẹ yi, awọn alaṣẹ ile ẹkọ gbọdọ wa ọna lati daabo bo awọn olukọ.

Ọkan lara ọna abayọ ti Olurotimi sọ ni pe ki wọn fun awọn olukọ ni idanilẹkọ to peye lori biba awọn akẹkọọ lo.