Unilorin Student Beats Lecturer: Ọmọ ti kọ́kọ́ bọ́ra sí hòhò l'àdúgbò kí o tó lọ lu Lẹ́ksọrà ní ọjọ́ kejì- Baba Captain Walz

Oríṣun àwòrán, Waliyu/ Instagram
- Author, Yemisi Oyedepo
- Role, Broadcast Journalist
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Bàbá Waliyu Anuoluwapo Salawudeen ti gbogbo ènìyàn mọ si Captain Walz ti ke gbàjarè pé kò yé òun ibi ti wàhálà yi ti n wa ti ọmọ oun fi n lu lẹ́kísọrà rẹ nilé ìwé.
Lásìkò tí bàbá náà ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, ọgbẹ́ni Salawudeen Tajudeen ṣàlàyé pé sáájú ni ọjọ́rú ni abúrò Waliyu to n jẹ́ Faruk ti kọ́kọ́ pé àkíyèsí òun.
Ó ni lẹ́yìn ti òun pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n òun jẹun tán ni ọ̀sán ni àwọn sùn, àti pé ni kété tí àwọn jí ni ó bọ́ si ìsàlẹ̀ ilé wọ́n ni àdúgbò ti wọ́n gba ilé sí.
- Kìí ṣe oògùn ni mo fi ń rántí déètì ọjọ́ àti oṣù lórí, ohun tí mo ṣe nígbà èwe rèé - Alaafin Oyo
- Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣe fẹ́ ẹ́ ta iléèṣẹ́ ọkọ̀ reluwé fún aládàáni
- Wọ́n gbé ẹyin ẹlẹ́yin IVF sínu obìnrin kan, àṣírí bá tú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ pé ọmọ ọlọmọ ló bí
- Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàrín Annie, ìyàwó 2face àti Pero, ìyá ọmọ rẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ oṣù méjì sẹ́yìn
- Charles Soludo ti jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra
Ìsàlẹ̀ yìí ló wà tí o lọ bọ́ ara rẹ si ìhòhò lójú pópó ti àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ni pé òun pe kí òun wá wó bi ẹ̀gbọ́n òun ṣe ń ṣe.
"Ìdi nìyí tí àbúro rẹ̀ ṣe pè mí ní ọ̀ja náà.
"Mó ṣáà sọ fún àbúrò rẹ̀ kó bá mi wá àwọn ènìyàn ki wọ́n díi mu nítorí ilẹ́ tí ṣú lọ́jọ́ náà ati pé tí ilẹ̀ bá ti mọ́ òun yóò ti maa bá ọkọ́ akọ́kọ́ bọ̀ wá sí Ilorin.
Bàbá Waliyu ni títí aago méjìlà oru ọjọ́ náà ni òun fi n pe àbúrò rẹ̀ láti mọ nǹkan tí o ń ṣẹlẹ̀.
Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí mo de ilé tí wọ́n gbé e lọ́jọ́bọ tí òun si pe abúrò rẹ̀ láti mọ ibi ti wọ́n wà, "àsìkò yìí gan ni àbúrò rẹ̀ tún sọ fún mi pé nǹkan mííràn má tún ti ṣẹlẹ̀.
"Faruk sọ fun mi pé Waliyu lọ si ọgbà Fásiti tí o sì lọ lu lẹkísọ́rà rẹ̀.
O ní àsìkò tí òun lọ kírun ní ìdáji ọjọ́ keji ni mọ́sálásí kan ti ó wà ni àyíká ilé àwọn ni òun wọle ti òun kò bá a mọ́.
Bàbá Waliyu ṣàlàyé pé Faruk ni ibi ti òun tí n wa kiri ni àwọn ọrẹ́ rl ti pe òun ni ilé iwé pé, waliyu ti lọ lu lẹ́kisọ́rà ni ilé ìwé.
"Kàyéfi ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún mi nítorí mi o ri irú èyí rí.
Irú ọmọ wo ni Waliyu láti ilé?
Àwọn ènìyàn ti BBC fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wo fi ìdí rl múlẹ̀ pé Waliyu kìí ṣe irú ọmọ bẹ́ẹ̀
Nínú ọ̀rọ̀ bàbá rẹ̀, o ni kìí se ọmọ tó buru tàbí tí o máa n hu ìwà burúkú tàbí gbé ojú sókè wo àgbàlagbà
Ní ti ọ̀rẹ́ rẹ ọkùnrin àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ obìnrin kan náà fi ìdí rl múlẹ̀ pé kìí ṣe ọmọ líle, wọ́n ni ẹni ti kìí fa wàhálà bákan náà kìí hu ìwà ipá.
Wọ́n ni orin kíkọ ló yàn laáàyo tí o si má n kọrin káàkiri ninu ọgbà ilé iwé wọn.
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti Bàbá rẹ̀ rọ àwọn aláṣẹ láti tún ṣe àyẹ̀wò fún láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ irú nǹkan ti ó n ṣe gan.
Díẹ̀ lára àwọn orin ti Waliyu tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Captain Walz
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
Níbo ni ọ̀rọ̀ dé dúró?
Bàbá Waliyu tó jẹ́ ọmọ́ bíbí ìpínlẹ̀ Kwara ni ilú Alo níjọba ìbílẹ̀ Ifẹlodun ṣàlàyé pé, títí ti on fi kúro ni ilé iwé náà ni ọjọ́ Ẹti ìkáwọ́ ilé iwé ni ọmọ náà wà kìí ṣe ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá.
Ọ̀jọ́bọ ni àwọn ẹka ètò àbó ilé ẹkọ́ Fasiti Ilọrin ni kí àwọn pàdà wá láti mọ ìdája ilé ẹ̀kọ́ náà.
Bábá Waliyu rọ gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà àti àwọn abiyamọ láti gbá ọ̀rọ̀ náà ro kí wọ́n wá ìdí ọ̀rọ̀ náà láti mọ nǹkan tí o ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ oun.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ́bìnrin kan tí o jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ṣàlàyé pé òun máá n ri pé ó n fa igbó, sùgbọ́n kìkí lo àwọn òògun olóró mííràn
Bákan náà ló fi kún pé lásíkò kan ó ti sọ fún oùn pé àwọn ọ̀rẹ́ ti ń di ẹ̀ru lé oun lọ́rùn jú.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ́bìnrin náà ṣe sọ, ó ni nígbà míkíràn ó máá n sọ̀rọ̀ bi éni pé ó fẹ́ ṣe òògùn owó.

















