Dontae Sharpe: Ọkùnrin tó lo ọdún 26 lẹ́wọ̀n fún ẹ̀sùn ìpànìyàn tí kò mọ nkankan nípa rẹ̀

Dontae Sharpe ti pada bori ninu ija to ja lati fi wẹ ara rẹ mọ kuro ninu ẹsun ipaniyan ti wọn fi ran lọ si ẹwọn lọdun 1994.
Ile ẹjọ ju Ọgbẹni Sharpe si ẹwọn gbere, nitori ẹsun ti wọn fi kan pe o pa ẹnikan, George Radcliffe.
Inu ọkọ akẹru rẹ ni awọn ọlọpaa ti ba oku George Radcliffe, pẹlu ọgbẹ ibọn ni agbegbe Greenville, nilu North Carolina lọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun 1994.
Lasiko igbẹjọ ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan, ọmọde kan Charlene Johnson jẹri tako o ,
Ninu ọrọ rẹ, o ni oun ri Ọgbẹni Sharpe, to jẹ alawọ dudu, bo ti ṣe yinbọn mọ Radcliffe to jẹ alawọ funfun lasiko ti ija waye laarin wọn nitori okoowo ogun oloro.
- 'Mi ò fìgbà kankan fura pé ọkọ mi lè fi ọmọ wa ṣe òògùn owó'
- Ọ̀pọ̀ arìnrìnàjò jóná, àwọn mìí tún farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Okitipupa
- Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rù n bà láti yọjú sílé ẹjọ́ dá ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha dúrò
- Ó lé ní àwọn elewon ẹgbẹ̀rún mẹta tí a ko tíì ri- Aregbesola
- Àlàyé rèé láti ẹnu ilééṣé ọlọ́pàá lórí ikú akọ̀ròyìn Vanguard, Tordue Salem
Agbẹjọro Sharpe, Theresa Newman sọ pe ọmọ to jẹri tako naa tun sọ pe lẹyin naa ni oun ri ti onibaara oun ati ọkunrin kan gbe oku Ọgbẹni Radcliffe sinu ọkọ naa, ti wọn si fi ọkọ naa kọlu ọgba kan, ki wọn to ju kọkọrọ rẹ nu.
Oṣu diẹ lẹyin igbẹjọ naa ni ọmọ naa sọ pe irọ ni ẹri ti oun jẹ nile ẹjọ.
O ni oun ko si ni tosi ibi ti ipaniyan ọhun ti waye,ati pe lati ori ara oun loun ti ṣe agbekalẹ ọrọ ti oun sọ nile ẹjọ.
Toun ti ọrọ ti ọmọde yi sọ, Dontae ko ṣi gba itusilẹ.O le ni ogun ọdun ki o to jajabọ kuro lọgba ẹwọn.
Awọn alaṣẹ pada tu Ọgbẹni Dontae silẹ ni oṣu Kẹjọ, ọdun 2019, lẹyin to ti lo ọdun mẹrindinlọgbọn ninu ẹwọn.
Gomina ipinlẹ North Carolina, Roy Cooper tun fun ni idariji lẹyin ọdun meji.

Oríṣun àwòrán, NORTH CAROLINA COURT
Pẹlu eyi, Ọgbẹni Sharpe yoo le beere fun owo itunu lọwọ ijọba.
O ni inu oun dun nigba ti ọmọ oun pe oun ni baba, ti awọn ọmọ rẹ naa pe oun ni 'grand pa'.
Inu ẹwọn ni Sharpe wa nigba ti wọn sọ fun pe iyawo rẹ ti bi ọmọbinrin kan.
Ko si ni anfaani lati ni ibaṣepọ kankan pẹlu ọmọ naa fun ọdun mẹrindinlọgbọn to lo ni ẹwọn.

Oríṣun àwòrán, others
O ni lootọ ni oun ti gba ominira, amọ ọpọ igba ni oun ma n ji sunkun laarin oru.
Dontae ko ti i pe ọmọ ogun ọdun nigba to lọ si ẹwọn. O si ti pe ẹni ọdun mẹrinlelogoji ko to o jade.
O sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa ko ri ẹri kankan to fihan pe oun lo pa ọkunrin alawọ funfun naa.

Oríṣun àwòrán, Aworan lati inu fidio
Bakan naa lo sọ pe ọmọbinrin kan jẹri pe ọrẹkunrin rẹ sọ fun ni alẹ ọjọ iṣẹlẹ naa pe oun yinbọn pa ọkunrin alawọ funfun kan, ṣugbọn oun ko fẹẹ lọ si ẹwọn.
O ni ọjọ diẹ lẹyin iṣẹlẹ naa ni ọrẹkunrin oun gbẹmi ara rẹ.
"Mo lero pe wọn o gba nkan ti obinrin naa sọ gbọ, tabi pe wọn mọọmọ ma gbagbọ."
"Ẹwọn ti mo lọ jẹ ki n mọ pe ọpọ lo wa ni ẹwọn fun ẹsun ti wọn o mọ nipa rẹ".












