Tordue Salem missing Vanguard reporter: Ọlópàá ṣé àfihàn afurasí tó mọ̀ nípa ikú akọroyin Tordue Salem,ẹ gbọ̀ òhun tó so

Oríṣun àwòrán, Others
Ileesẹ ọlọpaa ni Abuja ti tan imọlẹ sí ohun to ṣokunfa iku akọroyin kan t'awọn ẹbi rẹ ti n wa lati ọjọ meloo kan.
Lati ọjọ kẹtala oṣù Kẹwàá ni wọn ti ri arakunrin yi to jẹ akọroyin fún ileese iroyin Vanguard kẹyin.
Oun ni akọroyin ileeṣẹ iroyin naa ni ile aṣofin Naijiria nilu Abuja.
Lọwọ lọwọ bayi wọn tí gbé oku rẹ lọ sí ààyè igbokupamọ sí to wa ni ile iwosan nla Wuse ni Abuja
Iroyin bi Tordue se poora da wàhálà silẹ débi pe awọn akọroyin ṣe iwọde ni Abuja ti wọn sì kora jọ siwaju olu ileesẹ ọlọpaa.
- Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rù n bà láti yọjú sílé ẹjọ́ dá ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha dúrò
- Wo bí Pásítọ̀ ṣe ran bàbá lọ́wọ́ láti fi ọmọ rẹ̀ ṣe oògùn owó, ọká bá fó!
- Ìjọba Buhari, tí ẹ bá fẹ̀ yanjú ọ̀rọ̀ yìí ẹ jẹ́ kí Igboho lọ tọ́jú ara rẹ̀ ní Germany ná - Agbẹjọ́rò
- Wọ́n ní mo máa ń lọ bá ìyá tó bí mi sùn ní gbogbo ọjọ́ Tuesday, àṣírí ti tú, àwọn náà ti ń fojú balé ẹjọ́ o! - Genesis
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
Nkán bi ọjọ meji lẹyìn tí ilé aṣofin pe fún iwadii ekunrẹrẹ lori bo ṣe sonu ni iroyin bẹrẹ sí kan pe won ti ri oku rẹ.
Ki ni ọlọpaa lo ṣẹlẹ sí Tordue?
Agbẹnusọ ọlọpaa Frank Mba so fún àwọn akọroyin lọjọ Kejìlá osu kọkànlá pe ọkọ lo kọlu Tordue tó si ṣeeṣe ko jẹ pe ohun lo ṣokunfa ikú rẹ.
Ọlópàá ṣafihan afurasi kan to ṣalaye ohun tó ṣẹlẹ.
Oni takisi naa sọ pe "ni nkan bi ago mẹwaa alẹ ni mo fi ọkọ kọlù eeyan kan ladugbo Mabushi ṣugbọn mi o le duro nitori awọn adigunjale pọ ladugbo náà"
O tẹsiwaju pe nigba ti oun de adugbo Wuse ni oun kan sí awọn ọlọpaa to wa loju ọna ti wọn sì gba a lamọran pe ko lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa ṣugbọn ko lọ sibẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police
Ohun tó sọ pé òun ṣe ni pé "ni mo wa okoy li sí gareeji kan ti wọn pe ni Good Friend Garage ti mo sì gbé ọkọ kalẹ sibẹ."
Awakọ yi ni lọjọ Kejì loun to pada wa ti oun sí ri foonu kan toju rẹ fọ níbẹ.O loun ju foonu naa kalẹ tóun sì kuro ni gareeji naa.
Awọn ọlọpaa tọ ipasẹ foonu yi dé gareeji yi nibi ti wọn ni baba ọlọde kan ti ri he.
Wọn ni o fi siimu tuntun to ṣẹṣẹ ra sinu foonu naa.
Bẹẹ sì ni awọn ọlọpaa se mọ ibi ti foonu naa wa ati ohun tó ṣẹlẹ sí Tordue.
Mo ro pe ole ni lo mu kí n ma duro leyin ti mo fi ọkọ gba
Afurasí naa sọ pe idi toun ko fi duro lẹyìn toun fi ọkọ gba Tordue ni pé wọn ti já oun lole ri níbẹ.
BBC ṣi n fi ọkàn bá ìròyìn yí bọ.Kete ti a ba tun kẹfin nkan mi tó ṣẹlẹ la India to yin leti.












