Baba Ijesha rape case: Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rù n bà láti yọjú sílé ẹjọ́ dá ìgbẹ́jọ̀ Baba Ijesha dúrò

Baba Ijesha

Igbẹjọ Baba Ijesha lórí ẹsun biba ọmọdé wu ìwà tí kò tọ tun ti waye nile ẹjọ gíga ti ilu Eko lónìí.

Ṣaaju ni ile ẹjọ náà ti n retí awọn ẹlẹri méjì tí ìkọ olupẹjọ sọ pé àwọn yóò mú wa.

Ṣugbọn wọn sọ pé àwọn ko le mu awọn ẹlẹri náà wa síwájú adájọ fún àwọn ìdí kan.

Wọn ní ọkàn lára àwọn ẹlẹrìí náà ni ọlọ́pàá to ṣe ìwádìí ẹsun ti won fi kan Baba Ijesha, ṣugbọn kò lè yọjú nítorí iṣẹ ti gbé lọ sí àgọ ọlọpaa míràn.

Wọn tun sọ pe ẹru n ba ẹlẹri keji lati wa sile ẹjọ ni ko jẹ ko yọjú.

Lẹyìn náà ni wọn bẹ ile ẹjọ ọhun lati sun ẹjọ náà síwájú kí àwọn lè rí aye lati ko àwọn ẹlẹrìí náà wá.

Lẹyinorẹyin, adájọ Oluwatoyin Taiwo ti sun igbẹjọ náà sì ọjọ kokandinlogun, oṣù yìí, ati ọjọ keji, oṣù Kejìlá ọdún yìí.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu oṣù kẹrin ni wọn kọkọ fi ẹsun ifipa ba ọmọdé lopọ kan olujẹjọ, ìyẹn Baba Ijesha.

Ṣugbọn o ti sọ pé oun kò mọ nkankan nípa ẹsun ọhun, ati pe oun ko jẹbi