Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò Igboho ní ìjọba Benin kò tíì rí ẹ̀sùn ọ̀daràn kankan fi kàn án láti oṣù mẹ́ta tó ti wà lẹ́wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Abubakar Malami, SAN
Agbẹjọro Yomi Aliu(SAN) to n ṣoju Sunday Adeyemo Igboho nibi ẹjọ ti ijọba apapọ pe e ti fesi si ọrọ ti agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami sọ pe ijọba si le jeburẹ fi oṣelu yanju ọrọ naa.
Amọ Malami fidi rẹ mulẹ pe Igboho atawọn eeyan ti ọrọ kan ni lati kan si ijọba na lori ọrọ naa.
Ni ọjọ kẹwaa oṣu kọkanla ni Malami sọrọ yii nigba ti o n kopa ninu eto kan lori ẹrọ amohunmaworan Arise TV.
- Kwam 1 dá àwọn tó ń wọ́ ọ tuurutu nílẹ̀ pé ó jẹ́ gbèsè dollar iṣẹ́ orin kan l'Amẹ́rika
- Bó ṣe òṣèlú náà ló gbà, a léè fi wo ọ̀rọ̀ Sunday Igboho - Abubakar Malami
- Ẹ yéé gbé ìròyìn òfegè kiri nípa olóògbé Femi Osibona, ó ṣèlérí N25M fún ìjọ mi àmọ́... - Genesis
- Wọ́n ta ìkókó ọmọ mi ní N1M, wọ́n gbé abirùn ọmọ lé mi lọ́wọ́ - Obìrìn aláàrùn ọpọlọ figbe ta
- Wọ́n tún ti yọ òkú èèyàn méjì síi níbi ilé tó wó l'Eko, ó di èèyàn 45 tó kú níbẹ̀ báyìí
- Tí ó kó bá sùn ní aago yìí sí aago yii, àkóbá tí ò ń ṣe fún ìlera ọkàn rẹ nìyìí
- Taa ni arẹ̀wà obìnrin, Emmanuella Ropo tí ìròyìn n sọ pé òun ni ìyàwò K1 tuntun?
- Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrín ọmọ ìyá méjì ni Yobe, ni wọ́n bá gé ara wọn ní apá jábọ́.
Ṣugbọn ninu esi rẹ, Oloye Aliu ni Igboho dunnu si bi ijọba ti tun ero rẹ pa pe kii ṣe ipa lo le yanju ọrọ to wa nilẹ yii.
''Ijọba naa ti wa ri pe ọrọ awọn ẹya to beere fun iyapa lara orilẹede Naijiria kii ṣe ohun ti wọn le fi ipa mu.
Bi wọn ṣe n dunkoko mọ Igboho ti wọn gbe e ju si atimọle nilẹ okeere kọ ni ọna abayọ si ọrọ to wa nlẹ yii.
Ijọba gbọdọ bọwọ fun ofin eleyii ti ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki ijọba san ogun biliọnu naira fun Igboho lori ẹjọ to wa nilẹ yii.
Gbige ti wọn gbe ju si ẹwọn n fun un ni igboya sii lati teṣiwaju nipa bibeere fun iyapa orilẹede Yoruba lara Naijiria.
Lakọkọ naa ti ijọba ba n wa ọna abayọ si ọrọ Igboho, ki o kọkọ sọ fun orilẹede Benin ti o ka kun ipinlẹ kẹtadinlọgbọn Naijiria pe ko tu Igboho silẹ lati kọkọ lọ tọju ara rẹ na ni Germany.
Ijọba Benin ko tii ri ẹsun ọdaran kankan fi kan Igboho lati bi oṣu mẹta to ti wa lẹwọn lọna aitọ ni Cotonou,'' Aliu lo sọ bẹẹ.
Agbẹjọro Igboho ni onibara oun ti foun ni iyọnda lati buwọlu adehun pẹlu ijọba apapọ niwọn igba ti adehun naa ba ti tẹ ẹgbẹ Oodua rẹ lọrun.
Igboho ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ papa julọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ilana Yoruba/Oodua Nation nile ati nilẹ okeere.
Igboho n rọ gbogbo wọn lati tubọ tẹsiwaju lati maa bọwọ fun ofin ki wọn si maa fa wahala pẹlu ẹnikẹni.
Ọjọ kinni oṣu keje ọdun 2021 yii lawọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS yabo ile Igboho ni Ibadan nibi ti wọn ti ṣekupa eeyan meji ti wọn si ko eeyan mejila lọ si Abuja.
Ilu Cotonou lorilẹede Benin ni wọn ti mu Igboho nibi ti o ti n rinrin ajo lọ si Germany ti wọn si ju si atimọle.














