Jailbreak: Ó lé ní àwọn elewon ẹgbẹ̀rún mẹta tí a ko tíì ri- Aregbesola

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Others

Mínísítà ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Rauf Aregbesola tí ké gbàjarè pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹta ni àwọn sí ń wá, lẹ́yìn tí wọ́n sá kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọdún tó kọjá.

Lásìkò to ń bá àwọn oníroyìn eto kan tí ẹ̀ka ìròyìn nílé ìjọba l'Abuja gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ ru, ní Aregbesola tí ṣàlàyé pé ẹgbẹ̀rún mẹrin ati ọtaleniẹgbẹrin ẹlẹ́wọ̀n lo sá kúrò léwọn lọ́dún 2020, tí àwọn sí rí díẹ̀ dín ní egberun kan dá padà sí ẹ̀wọ̀n

Eyi túmọ̀ sí pé àwọn tó lè ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló wà níta báyìí.

Gẹ́gẹ́ bí Aregbesola ṣe sọ gbogbo àkọsílẹ̀ wọn lo wà nínú Bíbélì ìwé ìjọba, ìgbàgbọ́ sì ni pé ìgbésẹ̀ yìí yóò mú iṣẹ́ yá fún ìjọba àpapọ̀ láti rí wọn mú padà.

Minista náà ṣàlàyé pé ìkọlù sí àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n kan laipẹ yii n safihan eto àbò tó mẹ́hẹ ni Nàìjíríà

Ó ṣàlàyé pé ìjọba ń tọ pasẹ wọn tí wọ́n sì mú àwọn kan nínú wọn ní Ìpínlẹ̀ Imo. Ó fi ọkàn ara ìlú balẹ pé, ilé iṣẹ́ ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́ yóò ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yoo ṣètò bí wọn yóò ṣe mú wọn laipẹ yii.

Aregbesola ń sọ̀rọ̀ leyin ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí àwọn janduku ja ọgbà ẹwọn Abolongo n'ilu Oyo ti wọn si tú ọpọ ẹlẹwọn silẹ, títí di àsìkò yìí kò sí ẹni tó mọ iye àwọn tó sá lọ nibẹ.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ wáyé ní ìjọba so pé àwọn tí mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé nínú ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ kò ní pẹ́ ṣàwárí àwọn tó kọlu ọgbà ewon náà