Oyo Jailbreak: Wo ọṣẹ́ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Abolongo ṣe fáwọn ará Oyo àti bí wọn ṣe rí wọn mú
Yoruba bọ, wọn ni ki oju ma ri ibi, gbogbo ara ni oogun rẹ.
Eyi lo difa fawọn olugbe agbegbe ọgba ẹwọn Abolongo niluu Oyo kan ti wọn ti fi adugbo naa silẹ bayii lẹyin ti ado oloro mii tun bu gbamu nibẹ lọjọ Iṣẹgun.
Ọjọ Ẹti ọsẹ to lọ lawọn agbebọn yabo ọgba ẹwọn naa nibi tawọn ẹlẹwọn kan ti salọ lẹyin ikọlu to waye pẹlu oriṣiiriṣii ohun ija oloro.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- "Àwa ológun fipá gbàjọba ní Sudan láti dènà ogun abẹ́lé ni"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
- Ọmọ onílẹ̀ mẹ́ta kó sí páńpẹ́ ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Wo ohun tí Yinka Alaseyori sọ nipa Tope Alabi ní àyájọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Darandaran kan rí ẹ̀wọ̀n gbéré he ní Ekiti
- Nǹkan yan! Pásítọ̀ dáwọn ọmọ ijọ̀ dùbúlẹ̀ lórí pẹ̀pẹ́, ó ń nà wọ́n pẹ̀lú bẹ́lítì
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tó lù ará rẹ ní gbanjo ₦20m ní Kano
- Bí ìgbẹ́jọ́ Naira Marley ṣe lọ lọ́jọ́ Iṣẹ́gun rèé
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye fawọn olugbe adugbo pe awọn lo ṣee ti ado oloro tawọn agbebọn fi silẹ ninu ọgba ẹwọn bu gbamu ko o le ṣe akoba fawọn eeyan, awọn ara adugbo naa ni inu ibẹru-bojo lawọn wa.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si agbegbe Abolongo lati mọ bi awọn olugbe agbegbe naa ṣe wa lẹyin ibugbami ado oloro ẹlẹẹkeji nibẹ.
Alaga awọn olugbe agbegbe Abolongo ati arabinrin Ola adua ti oun naa n gbe adugbo yii ṣalaye fun BBC Yoruba pe ọpọ eeyan lo ti fi adugbo naa silẹ lẹyin ti ado oloro tun bu gbamu fun igba keji.
Ọkan lara awọn ọlọdẹ ilu Oyo to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe o ṣe pataki ki ijọba ro awọn ẹṣọ eleto abo lagbara nitori iru ikọlu bayii.
O ni ọpọ awọn ẹlẹwọn ni awọn ọlọdẹ ibilẹ n ṣà kaakiri nilu Oyo, ti wọn si pa meji lara awọ, ti wọn si ba isẹlẹ naa lọ.


