Nigeria Railway: Ìjọba Naijiria fẹ́ẹ́ ta iléèṣẹ́ ọkọ̀ reluwé fún aládàáni

Ọkọ reluwe

Oríṣun àwòrán, vanguard news

Minister keji fun eto irinna ni Naijiria, Gbemisola Saraki, ti sọ pe ijọba apapọ yoo ṣe atupalẹ ileeṣẹ ọkọ oju'rin, ti yoo si ta a fun awọn ileeṣẹ aladani.

Nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn olokkowo nilu Paris, lorilẹ-ede France lo ti sọ eyi.

O ni igbesẹ naa yoo mu ki orogún òwò wà ni ẹka irinna reluwe, ti yoo si mu idagbasoke ba awọn nkan amayedẹrun ni ẹka naa.

O kesi awọn oludokowo lati ilẹ okeere nibi ipade naa pe ki wọn o wa jẹ anfaani idikowo ni ẹka naa.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

O ni ṣiṣe bẹẹ yoo tun iyi ati ẹyẹ ẹka naa ṣe nile ati lẹyin odi.

"Eto imupadabọsipo ọlọdun mẹẹdogun to wa nilẹ wa fun atunṣe awọn oju'rin to ti wa tẹlẹ, ṣiṣe awọn oju'rin tuntun ati sisọ awọn ibudokọ oju'rin di ọtun.

Ikede Gbemisola Saraki waye lasiko ti awọn oṣiṣẹ reluwe n gbero iyanṣẹlodi ti yoo bẹrẹ ni Ọjọbọ.

Wọn n beere fun owo oṣu to dara, igbe aye irọrun ati eto aabo to peye fun awọn oju ọna reluwe.