A ò dí àwọn dókítà lọ́wọ́ láti má tọ́jú ẹni tí wọ́n yìbọn lù tàbí ẹni tó ní ìjàmbá mọ́tò

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà kí ké gbàjarè pé àwọn kò dí ilé ìwòsàn tàbí dókítà kankan lọ́wọ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ rí ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá kí wọ́n tó tọ́jú ẹni tí wọ́n yìn nibọn tàbí tó ní ìjàmbá ọkọ̀ kí wọ́n tó tọ́jú rẹ̀.
Ọ̀ga àgbà ọlọ́pàá Alkali Baba ló fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lasiko tó ń sọ̀rọ̀ níbi Ètò kan tí àwọn ẹgbẹ́ agbọ́jorò ni Nàìjíríà gbé kalẹ lórí ọ̀nà àti mójútó bí ará ìlú ṣe ń lo ibọn àti ìgbésẹ̀ tí àwọn ọlọ́pàá ń gbé
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti agbenusọ ọlọ́pàá ni Nàìjíríà Frank Mba ṣojú fún ṣàlàyé pé kò sí ìgbà kankan tí ọlọ́pàá tí di àwọn dókítà lọ́wọ́ láti máa tọ́jú ẹni tí ibọn ba bà, tí ó ní ìjàmbá oko tàbí tí wọ́n bá gún, kódà dókítà àti ọlọ́pàá jọ kunra wọn lọ́wọ́ șiṣẹ́ pọ̀ ni láti dáàbò bo ẹ̀mí ara ìlú
Frank Mba fi kun pé: "Àwọn Dókíta Nàìjíríà kò nílò ìwé àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá kí wọ́n tó tọ́jú ẹni tí wọ́n yìbọn mọ tàbí tó ní ìjàmbá ọkọ̀.
"Wọ́n ẹtọ láti tọ́jú àwọn ènìyàn, kí ni kété tí wọn bá tó gbé wọn dé kí wọn ṣe ìtọ́jú, leyin náà wọn lé pé ọlọ́pàá ni kíákíá bí Mba ṣe sọ.
Dókítà Idris to jẹ́ agbenuso fún ilé iwosan kan n'ilu Abuja sọ pé" yàtọ̀ sí ti ọlọ́pàá wàhálà náà tún ní ọ̀rọ̀ owó
"Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ọ̀kan pàtó lára ìdí tí gbọ́nmi-si omi-ò-to wà lórí ọ̀rọ̀ yìí láti ọdún 2017,nítorí tí tọ́jú ẹni tí wọ́n yìbọn yàtọ̀ sí títọ ju ẹni tí ó ní ààrùn ibà
Ó fi kún pé :" ó ṣeé ṣe kí ìbon tí wọn yín ènìyàn nílò ju isẹ ti dókítà kan yóò ṣe lọ tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò sì lọ tó oṣù kan ni ile iwosan láì sí owó yóò nira, tani yóò san owó náà.
- "Ọmọ kan ṣoṣo tó bí fún mi ni wọ́n gún lọ́dún mẹ̀ta sẹ̀yìn kí wọ́n tó gún òun náà pa báyìí"
- Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrín ọmọ ìyá méjì ní Yobe, ni wọ́n bá gé ara wọn ní apá jábọ́.
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, "Codiene", igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
- Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
Láti ọdún 2017 ni gbogbo àwọn ilé igbimọ̀ asòfin tí buwọ́lu tí tọ́jú ẹni tí wọ́n bá yìnbọn lù, láti mú òpin de ba ikú ọ̀wọwọ̀ọ́ láti ọwọ ibọn, ìjàmbá ọkọ̀, gígún ni lọ́bẹ àti pé kí wọn má máa kọ wọn nílé ìwòsàn pé afi kí wọn lọ gba ìwé àṣẹ wá láti ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá.
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn gbogbo òfin náà, àwọn agbẹjọ́rò sọ pé síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lọ ń kú nítorí rẹ.
Àwọn agbẹjọ́rò náà fi kun pé gbogbo ọmọ Nàìjíríà lọ ní eto láti wà láàyè, kódà kí ẹni náà wá ní bèbè ikú nítorí ibọn, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n dóòlà rẹ
Ọ̀pọ̀ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ lọ tí ní òtítọ́ yóò padà fojú hàn bóyá àwọn ọlọ́pàá sì ń dúnkokò mọ àwọn dókítà tó ń gbìyànjú láti dóòlà ẹni tí wọ́n yìbọn kí wọ́n to sọ fún ọlọ́pàá.












