Human Trafficking Series: Ìrírí àrábìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n tà wọ́n sí Lebanon àti Libya
Wọ́n ní bí a ò kú, iṣé o tán ni ìréti ìyá àti ọmọ rẹ̀ tí ìṣoro àìríná rílò tì dé oko ẹrú ìgbàlódé lórílẹ̀-èdè Libya àti Lebanon.
Adefunke Jesugbemi (èyí kìí ṣe orúkọ rẹ̀ ganagan) àti ọmọ rẹ sàlàyé pé lẹ́yìn ikú ọkọ ohún ní ìyà yìí pọ̀ fún òun àti àwọn ọmọ tí òun bí
Ó ṣàlàyé pé níbi tí o le de, ọmọ òun tó ti wa ni ipele kẹta ni fásiti ni láti kúro nílé ìwé nitor kò sí owó láti tẹ̀síwájú.
O ní èyí si lo fàá ti ọ̀rẹ́ òun fí dába pé kí òun rin irin ajo lọ sí orílẹ̀-èdè Canada láìmọ pé, oko ẹrú ni wọ́n gbé òun lọ.
Adefunke ko mọ̀ pé láti inú àgbada bọ́ sínú ayaran ni ọ̀rọ̀ òun yóò jẹ́.
Lẹ́yìn tí wan tan ìyá lọ sí orílẹ̀-èdè Lebanon tán, ní agent bá tún padà wọ́n mú ọmọ akọbi obinrin náà tó fi síle.
Ọ̀rẹ́ arábinrin yìí náà ló tún ṣe okùnfà bi ọmọ se ba sí ọwọ́ agent ti wọ́n sì tún ta òhun náà si Libya.
- 'Tí wọ́n bá bá ẹ sùn tí wọn ò "release" wọ́n á gba owó wọn, àwa la ń ra Kọ́ńdọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ń bá wa sùn ní Mali'
- Wo bí arábìnrin yí àti àwọn akẹgbẹ rẹ̀ yí ṣé n fí ìdárayá tún àyíká ṣé
- Gbogbo ayé wà ní ọdún 2021, àmọ́ 2014 ni Ethiopia ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀
- Ẹ ò lè jíròrò l'órílẹ̀èdè yín bẹ́ ò bá paná ìjà ogún tẹ́ẹ ṣì ń jà - Obasanjo
- Ọwọ́ ikọ̀ Amotekun tẹ afurasí ajínigbé tó n múra bíi wèrè ní gáréèjì Akure
- Ẹgbẹ́ Afenifere kò gbàgbọ́ nínú yíyapa kúrò ní Naijiria - Ayo Adebanjo
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí ọmọ pada de sí Nàìjíríà ló tó mọ̀ pé, òun ti lóyún sínú, sùgbọ́n Ọ̀ọ̀ni Ilé Ife, Ọba, Adeyeye, Enitan Ogunwusi tí gbà láti ṣàmọjútó ọmọ náà nígbà tí ó bá bii
Ọ̀rọ̀ kọ sísọ lásìkò tí àswọn méjèèjì ń sọ ìrírí wọ́n lóko ẹrú fún BBC News Yorùbá.

Oríṣun àwòrán, NEMA



