Plogging : Àṣà ìdárayá àti b'awọn ọ̀dọ̀ ṣé n lo láti fí ṣé àtúnṣe àyíká tó dọ́tì
Ni ile ẹkọ fasiti to wa ni ilu Ilorin, awọn akẹkọọ kan a maa ko ara wọn jọ lati ṣe idaraya loorekoore.
Idaraya nikan kọ ni wọn n ṣe, wọn tun fi akoko wọn ṣe atunsẹ ayika nipa ṣiṣa idọti eyikeyi to ba foju han.
Ninu awọn akẹkọọ yi ni Adeyemi Joy Ifeoluwa wa wọn a si maa pe aṣa imọtoto ati idaraya yi ni Plogging.
Ifeoluwa sọ nipa iriri rẹ ati bi Plogging ti ṣe jẹ ki o rọrun fun oun lati kopa ninu idaraya.
O ni ṣaaju igba yi, a ti ṣe idaraya jẹ nkan to le ṣugbọn bayi toun ti pa pọ pẹlu Plogging, irọrun lo ba de.
''Gbogbo awọn exercise ki eeyan maa na apa ki eeyan maa na ẹsẹ, mi o mọ ṣe rara''
Ọdun 2018 ni wọn bẹrẹ ẹgbẹ Plogging Naijiria ni fasiti Obafemi Awolowo.
O ni anfaani fun ilera ara paapa fun iru Ifeoluwa to ṣe pe o n jẹ igbadun nipa ara rẹ ju tatiẹyinwa lọ.