Ethiopia: Orílẹ̀èdè tó ní oṣù mẹ́tàlá,, tó tún jẹ́ ibi tí Àpótí Ẹ̀rí Israel wà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ kinni, oṣu Ṣẹrẹ (January) ni ọpọ awọn orilẹ-ede lagbaye ma n ṣe ajọyọ ọdun tuntun.
Ṣugbọn ni oril-ede Ethiopia, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan ni wọn maa n bẹrẹ ọdun tuntun ti wọn.
Orilẹ-ede yii jẹ ibi kan to yatọ si awọn orilẹ-ede agbaye to ku.
Kini idi to fi jẹ bẹ ati pe iru ayẹyẹ wo ni wọn maa n ṣe lajọyọ ọdun tuntun?
Mọ si nipa awọn nkan to mu Ethiopia yatọ si awọn orilẹ-ede yooku ni agbaye.
1. Oṣu mẹtala lo wa ninu ọdun ti wọn
Kii ṣe eyi nikan o - Kalẹnda ti Ethiopia n lo paapaa yatọ si eyi ti gbogbo eeyan n lo. Lọwọlọwọ, ọdun 2014 ni orilẹede naa wa bayii.
Ọjọ Satide, ọjọ kinni, oṣu Kọkanla ni wọn bẹrẹ ọdun tuntun.
Idi ni pe wọn n ṣe onka ọdun ibi Jesu Kristi lọna to yatọ. Nigba ti ijọ Aguda ṣe atunsẹ si onka rẹ ni ọdun 500 AD, ijọ igbaani ni Ethiopia ko sẹ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni awọn orilẹ-ede kan, awọn ọmọde ma n kọ akọsori nipa iye ọjọ to wa ninu oṣu kọọkan.
Ṣugbọn ni Ethiopia, ko si nkan to n jẹ bẹẹ: Ọgbọn ọjọ lo wa ninu oṣu mejila, ti oṣu kẹtala to kẹhin ọdun si ma n ni ọjọ marun-un tabi mẹfa.
2. Orilẹ-ede Ethiopia nikan ni wọn ko mu ni ẹrú ni Africa
Orilẹ-ede Italy gbiyanju lati wọ Ethiopia, to n jẹ Abyssinia lasiko naa, ni ọdun 1895.
Asiko yii ni awọn orilẹ-ede lati Yuroopu n pin ilẹ Africa mọ ara wọn lọwọ.
Ṣugbọn, idojuti ni Italy ba kuro ni Ethiopia.
Wọn gbiyanju lati fi ọgbọn wọle si Ethiopia, nitori pe wọn ti ṣẹgun Eritrea to wa ni ẹgbẹ rẹ. Wọn ba tii fun ọpọlọpọ ọdun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣugbọn, Ethiopia ṣẹgun wọn loju ogun ti a mọ si Battle of Adwa.
Ẹgbẹẹgbẹrun ikọ ogun Italy lọna mẹrin ni awọn ọmọ ogun Ethiopia ṣẹgun wọn laarin wakati diẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹta, ọdun 1896.
Asiko Ẹmpẹrọ Menelik II ni ogun naa waye.
Wọn fi ipa mu Italy lati fi ọwọ si iwe adehun pe oun ko ni dan iru rẹ wo mọ.
Ọkan lara awọn Ẹmpẹrọ to jẹ lẹyin Menelik, Haile Selassie, lo anfaani iṣẹgun ti wọn ni lori Italy lati beere fun idasilẹ ajọ iṣọkan ilẹ Africa, Organisation of African Unity (OAU), to ti di African Union bayii.
Ilu Addis Ababa to jẹ olu ilu Ethiopia si ni olu ileeṣẹ rẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Ethiopia ni Apoti Ẹri awọn ọmọ Isirẹli wa
Ni igbagbọ ọpọ ọmọ orilẹ-ede Ethiopia, Apoti Ẹri, ninu eyi ti ofin mẹwa ti Ọlọrun fun Mose wa, ko sọnu.
Ijọ Igbaani ni Ethiopia sọ pe Apoti Ẹri naa wa ni abẹ ìṣọ ati abo ni gbogbo igba, ninu ile ijọsin Our Lady Mary of Zion Church niluu Aksum, nibi ti ko ti si aaye fun ẹnikẹni lati ri i.
Itan sọ pe Apoti Ẹri naa bọ si ọwọ ile ijọsin ọhun nipasẹ Ayaba Sheba.
Igbagbọ awọn eniyan orilẹ-ede Ethiopia ni pe lati Aksum lo ti rinrinajo lọ si Jerusalẹmu lati ri Ọba Solomọni lati mọ nipa ọgbọn ti iroyin sọ pe Solomọni ni, ni nkan bi ọdun 950 BC.

Itan naa to wa ninu iwe Kebra Nagast sọ nipa bi Makeda, Ayaba Sheba, ṣe bi ọmọkunrin kan, Menelik (to tumọ si ọmọ ẹni to gbọn), fun Solomọni.
Ati bi ọmọ naa ṣe rinrinajo lọ si Jerusalẹmu lẹyin ọpọ ọdun, lati lọ mọ baba rẹ.
Akọsilẹ itan naa sọ pe Solomọni fẹẹ ki ọmọ naa duro, ko si jọba lẹyin iku rẹ, amọ o ni oun n pada lọ si ile lọdọ iya oun.
Ọkan lara awọn ọmọ Isirẹli ti Solomọni yàn pe ko tẹle pada, lo ji Apoti Ẹri naa gba, to si fi ayederu rọpo rẹ.
Nigba ti aṣiri tu si Menelik lọwọ, o gbà lati gbe e pamọ, nitori igbagbọ pe eto Ọlọrun ni pe ki apoti naa duro ni Ethiopia.
Pẹlu agbara ati ẹmi si ni awọn Kristiẹni ijọ Igbaani ni Ethiopia fi n pa apoti naa mọ.
4. Ethiopia tun ni ibi akọkọ ti awọn Musulumi tẹdo si yatọ si Arabia
Itan sọ pe lasiko ti Anọbi Muhammed n koju idẹyẹsi nilu Mecca, nigba to ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni i waasu, o sọ fun diẹ lara awọn ọmọ ẹyin rẹ pe ki wọn o lọ si ilu kan to n jẹ Abyssinia, "ẹ o ri ọba kan ti ko faaye gba ifiyajẹni".
Awọn eniyan naa gba imọran rẹ, wọn si lọ si Aksum, nibi ti Ọba Armah, to jẹ Kristiẹni ti ki wọn kaabọ, ti wọn si fi aaye gba wọn lati ṣe ẹsin wọn.
Abule Negash ti wọn fun wọn nigba naa lo ti di Tigray bayii, nibi ti awọn arinrinajo naa kọ mọṣalaaṣi ti awọn kan sọ pe oun lo ti pẹ julọ ni Africa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Amọ, ni ọdun to kọja, ado oloro wo mọṣalaaṣi naa lasiko ogun to waye ni Tigray.
Awọn Musulumi ni ilu naa tiẹ gbagbọ pe ọmọ ẹyin Anabi mẹẹdogun ni wọn sin si ilu Negash.
Irinajo si Aksum si ni Hijra akọkọ ninu akọsilẹ itan Islam.
Lonii, ida mẹrinlelọgbọn awọn eeyan to wa ni orilẹ-ede Ethiopia lo jẹ Musulumi.
















