Wrong IVF: Àlàyé rèé bí ilé ìwòsan IVF ṣé páàrọ̀ ẹyin m tọkọtaya lọ́wọ́, ọjọ́ ikunlẹ́ làṣírí tú pé ọmọ ọlọmọ ní wọn bí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ọmọ tí wọ́n páàrọ̀ ẹyìn rẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ ní mo fí oṣù mẹ́ẹ̀sán gbáko gbé oyun rẹ sínú".
Tọkọtaya kan ni California ti gba ile ẹjọ lo lẹyìn tí ileesẹ to n ṣètò iranwọ fawọn to ba ni ìṣòro ọmọ bibi nipasẹ eto IVF gbe ẹyin ọmọ ọlọmọ fún wọn gẹgẹ bi tiwọn.
Daphna ati Alexander Cardinale sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn loṣu Kẹsán ọdún nigba t'awọn ri pe ọmọ tàwọn bi ko foju ju awọn rara ati rara.
Lẹyìn ayẹwo DNA,won rí pe tọkọtaya miran ti wọn ṣe eto IVF fún lasiko kanna pẹlu awọn ni ile iwosan lo ṣe pasiparo ẹyin mọ awọn lọwọ ti wọn sì bí ọmọ obinrin ti wọn rọpo eyi tó jẹ ti wọn gangan.
Igba àkọkọ kọ ni yi ti iru nkan bayi yoo ma waye.
IVF jẹ eto ṣiṣe iranwọ ọmọ bíbí fún tọkọtaya eleyi ti wọn a máa fi ìlànà ètò sayensi ode oni gba aatọ ọkọ àti eyin iyawo rẹ ninu laabu ti wọn a sì ṣe iṣẹ lori rẹ ki wọn to gbe sinu iyawo lati le gbe gẹgẹ bi oyun.
Tọkọtaya Cardinales ni awọn n pe ileesẹ ilera to ṣètò iranwọ ọmọ bibi yi ti orukọ rẹ n je.
California Center for Reproductive Health (CCRH), ati laabu VitroTech Labs,to ṣètò bi wọn ṣe gba ẹyin ati aatọ awọn.
Ninu ẹjọ ti wọn pe,wọn ni awon fẹsun aiṣedede ati aibikita awọn eleto ilera yi tó mú kí wọn fi ọna eru gbe ẹyin ọmọ ọlọmọ fawọn.
Ko sí ikankan ninu awọn ileesẹ wọn yi to gba lati fesi sí ibeere lati ile iṣẹ iroyin wà BBC.
Lasiko ti tọkọtaya yi n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje, arabinrin Cardinales ni iporuru ọkan ba àwọn lori iṣẹlẹ yi tawon ko sí mọ nkan ti eeyan le ṣe.
"Titi laelae ni a o maa ranti pe ọmọ ọlọmọ la finu ṣoyun rẹ àti pe ọmọ tó yẹ kí a gbé oyun rẹ, wọn gbe fún ẹlòmíràn"
Arabinrin Cardinale sọ pe wọn ja oun lole anfaani to yẹ kí òun ni lati le "finu gbe oyún ọmọ toun gangan'
Ninu iwe ipẹjọ wọn ṣalaye pe ọdun 2018 láwọn kan sí ileesẹ ilera iranwọ ọmọ bibi yi.
Arabinrin Cardinale sí bí ọmọ ọlọmọ ni ọdun to tẹle.
Ninu iyara igbẹbi nise lo je iyalẹnu fún wọn nígba tí wọn rí pe ọmọ tó jáde kó fi àwọ jọ awọn rara ati rara.
Kaka ki ọmọ naa jẹ alawọ funfun bi akọbi awọn nise ni awon ri pe alawọ dudu lo jẹ.
Ọkọ iyawo sọ pe oun ni lati tadi mẹyin nigba toun foju ri omi to jade lara iyawo oun.
Lẹyìn oṣù meji wọn ṣe ayẹwo DNA eti to pada fi hàn pe ọmọ naa kii ṣe tiwọn.
Arabinrin Cardinale sọ pe nise ni ooyi bẹrẹ si ni kọ òun tí gbogbo araye oun ko sí mọ nkan ti n lọ layika mọ nígbà tí esi ayẹwo DNA naa jade.
Ileesẹ ilera ti wọn lọ pada wa bawọn tọ pínpín tọkọtaya to gbe oyún ọmọ tiwọn paarọ.
Oṣù mẹrin lẹyìn ìgbà to d'aye ni awọn Cardinales to wa pada foju ri ọmọ wọn gangan.
Lẹyìn ọpọ ipade wọn fẹnu ko pẹlu awọn tọkọtaya keji lati paarọ ọmọ pada lọdun 2020.
"Kaka ki n fun ọmọ mi lọmu, ọmọ ẹlòmíràn ni mo wa n tọju bi témi.Mo fi ìfẹ hàn sí ọmọ ọlọmọ ti wọn padà gba lọwọ mi"
Alaye ree lati ẹnu arabinrin Cardinales fawọn akọroyin tó sì tẹsiwaju pe ọmọ tàwọn bi tẹlẹ to jẹ ọmọ ọdún meje naa faragba ninu inira yi.
Wọn ni ọrọ naa rú lójú pé àwọn ni lati parọ ọmọ tó ti rò pe aburo oun nii ṣe.
Ati ọkọ àti iyawo ni wọn ti n gba itọju lọdọ awọn to mọ nípa aarun ọpọlọ nitori iru iporuru ọkan ti iṣẹlẹ yi ko ba wọn.
Agbẹjọro wọn ṣalaye pe tọkọtaya keji ti ọrọ yi kan naa n gbèrò lati pẹjọ ṣugbọn wọn kò ní darukọ wọn.
Lọdun 2019 iru nkan bayi sele si idile miran ni California nigba ti wọn rí pe awọn ẹlomiran lo bi ọmọ tó yẹ kó jẹ tàwọn ni ilu New York.
Wọn pe arabinrin to gbe oyun ọmọ naa sinu lẹjọ nitori o kọ láti gbe ọmọ wọn kalẹ.
Adájọ pada ni ki o gbe ọmọ fun ọlọmọ.
















