Rivers Pastor kills wife:Ṣé lóòótọ́ ní pé Pásítọ̀ yí Chris fún ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn pa nítorí owó?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Elvis Opurum

Pasitọ Chris Amadi ti ijọ Shalom Mercy Ministry to wa niluu Aluu, ni ipinlẹ Rivers ti wa ni gbaga ọlọpaa bayii lori ẹsun pe o fun iyawo rẹ lọrun pa.

Iroyin ni Amadi ti kọkọ gbiyanju lati fẹsẹ fẹ lẹyin iṣẹlẹ naa ki ọwọ ofin to ba.

Awọn oṣojumikoro kan ninu ẹbi oloogbe naa sọ fun awọn akọroyin pe wahala bẹ silẹ lori ọrọ owo ti wọn n pa wọle lati ile ẹkọ ti wọn da silẹ lorukọ oloogbe naa, Solution International School.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, obinrin ọhun lo da ile ẹkọ naa silẹ ko to ṣe igbeyawo pẹlu afurasi lọdun 2012.

Wahala bẹrẹ lasiko ti Solution, iyẹn oloogbe, bere lọwọ ọkọ rẹ idi ti yoo fi le awọn akẹkọọ̣ kan kuro nile ẹkọ naa nitori pe wọn ko tii san owo ile ẹkọ lai kọkọ bere lọwọ oun.

Ẹgbọn oloogbe, Odinaka Opurum ṣalaye fun awọn akọroyin pe oloogbe naa koro oju si ọkọ rẹ lẹyin ti awọn obi kan bẹrẹ si ni pe lori ago lati fi ẹjọ ọkọ rẹ sun pe awọn korira iwa to n wu si awọn ọmọ wọn.

Aworan Ile ẹkọ to da wahala silẹ

Oríṣun àwòrán, Elvis Opurum

Àkọlé àwòrán, Ile ẹkọ to da wahala silẹ

O ni "Ọkọ rẹ lọ sile ẹkọ naa lọjọ Kẹsan an, oṣu yii lati le awọn akẹkọọ kan kuro nibẹ nitori gbese ti wọn jẹ ṣugbọn awọn obi awọn ọmọ naa bẹrẹ si n pe iyawo lati bere eredi ti yoo fi le awọn ọmọ pada sile, o si ṣeleri lati ṣe iwadii lọwọ ọkọ rẹ."

"Nigba to dele to bere bi ọrọ ṣe jẹ lọwọ ọkọ ni ija bẹrẹ ti okunrin ọhun si bẹrẹ si n lu, asiko naa lo tẹ lọrun mọlẹ titi to fi daku."

"Lẹyin to daku tan lo gbe digbadigba lọ sile iwosan kan to wa lẹba ile ti wọn n gbe, ibẹ ni wọn ti sọ fun obinrin naa ti dakẹ."

Aworan Tọkọtaya ati awọn ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Elvis Opurum

Àkọlé àwòrán, Tọkọtaya ati awọn ọmọ wọn

"Bo tilẹ jẹ pe wọn gba niyanju pe ko gbe lọ sile iwosan UPTH ṣugbọn kaka ko ṣe bẹẹ, ni ṣe lo gbe pada sile wọn, to si ko awọn aṣọ rẹ kan ni igbiyanju lati na papa bora."

Opurum sọ siwaju pe kii ṣe igba akọkọ ree ti okunrin yii yoo lu iyawo rẹ nilu bara, ṣugbọn obinrin naa n foriti nitori ifẹ to ni si ọkọ rẹ .

Bẹẹ ko fẹ kọ ọkọ rẹ silẹ lọna ati jẹ apere rere fun awọn ọdọ ijọ wọn.

Ọdun 2012 ni tọkọ-taya naa ṣe igbeyawo, wọn si bi ọmọ obinrin meji ati okunrin meji.