Bode George vs Tinubu: Igbokwe képe Bode George láti jèbùrẹ́, kó sì fa Tinubu mọ́ra

tinubu ati bode george

Oríṣun àwòrán, other

Alukoro ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko tẹlẹ, Joe Igbokwe ti rọ awọn alẹnulọrọ nipinlẹ Eko lati yanju gbọmi sii omi o to to wà laarin Asiwaju Bola Tinubu ati eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George.

Igbokwe ni lati ọdun 1999 ti orile-ede Naijiria ti pada si ijọba awaarawa ni ọrọ Tinubu ati Oloye George ko ti wọ rara.

"Loju bayii ni awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko lati ọdun 1999 ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu AD, AC, ACN ati APC bakan naa.

Oloye Bode George nikan ni eekan ẹgbẹ oṣelu PDP ti ko darapọ mọ ọkàn kan ninu awọn ẹgbẹ yii.

Bode George ti gbiyanju, o si ti fihan pe ọkunrin mẹta nii ṣe.

Ati pe o ti fihan gbogbo eeyan pe ẹni to maa n duro lori ipinnu rẹ ni i ṣe.

Amọ, ko yẹ ki Oloye Bode George maa fi akoko rẹ ṣofo lori aawọ ati iyapa.

O yẹ ki Oloye Bode George gbe ọrọ yii yẹwo ki o si ṣe ohun to tọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ọkùnrin mẹ́tà ló timi mọ́lé tí wọ́n n bá mi sùn lójoojúmọ́ ni Libya

Titako Asiwaju ni gbogbo igba ko le mu nkan kan wa.

Ti ọmọ ẹni ba dara, ẹ jẹ ka sọ, ti eeyan ba ju wa lọ bakan naa, ẹ jẹ ki a gba fun un.

Ọga mi, ika o dọgba, ẹ jẹ ki a gba fun ọga.

Gbogbo eeyan ni Asiwaju nilo to fi mọ Bode George lati tẹsiwaju ninu Irinajo oṣelu rẹ.

Idi gan an niyii ti mo fi n rọ awọn eekan ilu nipinlẹ Eko lati pẹju si ija to wa laarin Tinubu ati Bode George," Igbokwe lo sọ bẹẹ.