Timothy Adegoke: Mi ò tíì rí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa ọkọ mi - Ìyàwó olóògbé

Oríṣun àwòrán, livetimesng
Iyawo Timothy Adegoke, akẹkọọ OAU to ku sile itura Hilton, ni Ile Ife ti ke gbajare lori oniruru esi ayẹwo iku to pa ọkọ rẹ to n jade.
Esi ayẹwo iku to pa okunrin naa ti fa oniruru awuyewuye bayii, paapaa lati ọdọ awọn mọlẹbi oloogbe ati mọlẹbi awọn ti wọn fẹsun kan.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi esi ayẹwo naa lede, ohun to fa awuyewuye ko ṣẹyin ohun ti wọn ni o fa iku Timothy ninu ọkan lara awọn ẹda esi naa to ti wa ni igboro.
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
- Ọkọ mi ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò pa ara òun, àmọ́ ẹbí kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí - Ìyàwó ọkùnrin tó bẹ́ sí odò ọ̀sà
- Ọmọ oṣù mẹ́fà tí ìròyìn sọ pé ọ̀gá ìyá rẹ̀ fi ipá gbà nítorí gbèsè nílùú Eko ti padà kú
- 'Mi ò rí ọkùnrin bá lòpọ̀ fún ọdún kan gbáko lásìkò "lockdown" àmọ́ mo dán ǹkan wò'
Opó Timothy Adegoke sọ fun awọn akọroyin pe awọn to n ṣe iwadii iku ọkọ oun ko tii sọ fun oun ohun to ṣekupa ọkọ rẹ ni pato.
O ni "A ṣi wa lori ọrọ naa, ẹnikẹni ko dunkoko mọ mi, ṣugbọn wọn n dunkoko mọ ẹgbọn ọkọ mi, iyẹn Gbade Adegoke."
"Wọn ti gbiyanju lati ji ẹgbọn ọkọ mi gbe ni nnkan bii ọjọ mẹrin sẹyin."
"Awọn ọlọpaa sọ fun wa pe awọn yoo kede esi ohun to ṣokunfa iku rẹ, ṣugbọn mi o tii gbọ nnkankan nipa rẹ titi di akoko yii."
Gẹgẹ bii ohun ti obinrin naa sọ, awọn ẹbi Adegoke ti gbọ pe esi ayẹwo naa to wa lode yoo mu inu wọn dun lori bi oloogbe naa ṣe jade laye, yoo si tun tu aṣiri bi o ṣe ku atawọn to lọwọ ninu iku rẹ.
O ni "Awọn ọlọpaa sọ fun wa pe awọn ti ni esi naa lọwọ amọ ako mọ ohun to wa ninu rẹ."
O han gbangba pe ṣe ni wọn pa ọkọ mi, idi ree ti a fi ke pe ẹni ti yoo ṣe ayẹwo ni iha tiwa."
"Ọkọ mi lọ ṣe idanwo, o lọ sile itura lati sun, ibẹ naa ni wọn ti ṣekupa a... a ni ẹri to dantọ lọwọ lati fi idi ọrọ yii mulẹ."
Ẹwẹ, agbẹjọro ẹni to ni ile itura ti oloogbe naa ku si, Abiodun Williams ti sọ pe wọn ko ṣe ayẹwo miran lẹyin eyii ti wọn ti kọkọ ṣe ṣaaju lodi si iroyin to n lọ ni igboro.
Timothy Adegoke jade laye lẹyin to wọ sile itura Hilton, to wa ni Ile Ife lọjọ karun un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 yii.
Ẹni to ni ile itura naa, Ramon Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ kan ti wa ni ahamọ ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun ni bi iwadii ṣe n lọ lọwọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ramon Adedoyin kò gbọdọ̀ kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá o, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fohùn ránṣẹ́ s'ọ́gá ọlọ́pàá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Ramon Adedoyin/ timothy adegoke/facebook
Awọn ẹbi Oloye Ramon Adedoyin to ni ile itura Hilton Hotel ti akẹkọọ eto ẹkọ imọkun'mọ Masters ti fasiti OAU nilu Ile ifẹ, Timothy Adegoke ku si loṣu kọkanla ti ke gbajare tọ ọga ọlọpaa patapata lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba pe ko gbọdọ jẹ ki Oloye Adedoyin ku si ahamọ ọlọpaa pẹlu bi akitiyan awọn agbẹjọro rẹ lati gba beeli rẹ ṣe n ja si pabo.
- Omidan tó ń wọ Hijab gba adé arẹwà Miss Nigeria fún ìgbà àkọ́kọ́
- Ta ló kán gbajúmọ̀ òṣèré, Nkechi Blessing Sunday lẹ́sẹ̀?
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Ìròyìn òfegè lásán ni! Ilé ẹjọ́ kò gba agbára lọ́wọ́ àwọn ibùdó ìgbéyàwó tí a dá sílẹ̀, ẹ m'ẹ́nu kúró lórí Ikoyi Registry
- Cute Abiola: A ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni, ẹ máa rétí àwọn "Skits" tó gbaski
Ni ọjọ karundinlogun oṣu kọkanla ni awọn ọlọpaa mu Ramon Adedoyin lori iwadii iku to pa Adegoke si ile itura rẹ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, awọn ẹbi Adedoyin n ke si ọlọpaa lati fi aye silẹ fun beeli rẹ tabi ki wọn gbe e lọ si ile ẹjọ nibi ti anfani wa fun un lati wi awijare rẹ.
Atẹjade naa jẹ ko di mimọ pe, lati bii ọgbọn ọjọ o le diẹ sẹyin ti wọn ti mu u si ahamọ ẹsun kan ṣoṣo ti wọn n tẹnumọ lori rẹ "ti awọn ko si mọ bo ṣe jẹ ẹṣẹ - ni pe oun lo ni ile itura naa pẹlu bi awọn iroyin to n jade ṣe n fidi rẹ mulẹ pe ko lọwọ ninu bi akoso ile itura naa ṣe n lọ."
Wọn ni gbogbo bi awọn agbẹjọro rẹ ṣe n gbiyanju lati gba oniduro rẹ lawọn ọlọpaa naa n yi wọn sihin ati si ọhun pẹlu oniruuru awawi ati gbedeke.
Wọn ni o fi han gedegbe pe awọn alagbara kan lo wa nidi bi Ramon Adedoyin ṣe n wa lahamọ, ẹru si n ba awọn pe pẹlu ilera rẹ ki ohun ti awọn ko fẹ ma lọ ṣẹlẹ sii.
















