Ikoyi Marriage registry: Ìjọba àpapọ̀ fèsì lórí nkán tí ìdájọ ilé ẹjọ gíga sọ nípa ẹni tó lágbára láti darí àwọn ibùdó ìgbéyàwó

Ile ẹjọ iṣegbeyawo

Oríṣun àwòrán, Ministry of interior

Ijọba apapọ Naijiria ti fesi tako ọrọ to gbode pe ko ba ofin mu fawọn lati maa ṣeto igbeyawo lawọn ibudo igbeyawo taa mọ si registry.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n risi ọrọ abẹle fi sita lọjọ Iṣẹgun ni ọrọ yi ti jẹyọ.

Wọn ni irọ ni ọrọ yi ti awọn to si gbe kalẹ n sọ lati ṣe araalu lọna nipa idajọ ile ẹjọ giga lori ẹjọ ti ijọba ibilẹ Eti Osa gbe wa ni itako bi ijọba apapọ ṣe n ṣeto igbeyawo.

Dr Shuaib Belgore to jẹ akọwe agba ileeṣẹ naa sọ pe ninu idajọ yi, ile ẹjọ giga to wa ni Ikoyi sọ pe ijọba apapọ lẹtọ lati ṣeto ọrọ igbeyawo lai si idiwọ.

O ni ijọba apapọ gẹgẹ bi idajọ naa ṣe sọ lo gbe agbara fun ijọba ibilẹ lati fun awọn eeyan ni iwe ẹri igbeyawo lorukọ rẹ labẹ ofin to de igbeyawo ni Naijiria.

O tẹsiwaju pe kaka ki wọn tako idajọ yi, ohun ti ijọba ibilẹ to gbe ẹjọ yi wa ṣe ni pe wọn tun lọ pe iru ẹjọ yi nile ẹjọ giga miran.

Tori naa Belgore sọ pe ile ẹjọ fọwọ rọ ẹjọ yi danu pe wọn kole maa gbe ọrọ kanna wa si ile ẹjọ giga meji ọtọọtọ.

Aworan oruka igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lori ayelujara ati kaakiri aaye miran ni Naijiria ni ọrọ ẹni to laṣẹ lati ṣeto igbeyawo yi ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Bawọn kan ṣẹ n sọ nisọ awada pe ọpọ igbeyawo ti wọn ṣe ni Registry Ikoyi ni idajọ yi sọ pe ki wọn wọgile lawọn miran n beere pe ṣe ọrọ aaye igbeyawo lo kan ninu ọrọ ilẹ yi.

Ohun to mu ki orukọ ''Registry Ikoyi'' gba nu awọn eeyan kan nipe ibudo yi lọpọ to ba fẹ gba iwe ẹri igbeyawo latifi ṣeto irina lọ si ilẹ okere maa n lọlati ṣe igbeyawo wọn.

Ayédèrú ni gbogbo ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe ní Ikoyi Registry àti àwọn míì

Ile ẹjọ iṣegbeyawo

Oríṣun àwòrán, Ministry of interior

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ kan nipinlẹ Eko ti kede ti kede pe ko ba ofin mu fun ijọba apapọ lati seto igbeyawo.

Onidajọ D. E. Osiagor to dajọ naa sọ pe awọn ijọba ibilẹ nikan ni ofin ọdún 1999 fun ni agbara lati ṣe bẹẹ.

O ni ijọba ibilẹ lo ni àṣẹ lati so ọkọ ati iyawo pọ, to si le fun wọn ni iwe ẹri igbeyawo.

Onidajọ Osiagor sọ pe ikọja aye ni bi ijọba apapọ, nipasẹ ileesẹ ọrọ abẹle ṣe da awọn ibudo igbeyawo bii Ikoyi Registry silẹ.

O ni nitori naa, àwọn igbeyawo ti wọn ṣe nibẹ ko lẹsẹ nilẹ rara.

Bakan naa lo pàṣẹ pe ki wọn o ti gbogbo àwọn ibudo igbeyawo ti ileesẹ ijọba naa da silẹ, to fi mọ ti Ikoyi pa ni kiakia.

O ti to asiko díẹ̀ ti ede aiyede ti n waye laarin awọn ijọba ibilẹ kan ni Naijiria ati ijoba apapọ lori ẹni to ni agbara lati ṣe isopọ igbeyawo tabi fun ni ni iwe ẹri igbeyawo.

Eyi lo si mu ki ijọba ibilẹ Eti-Osa nipinlẹ Eko, lọ sile ẹjọ lati gba agbara isakoso ibudo igbeyawo to wa ni agbegbe Ikoyi, Ikoyi Registry ti ileesẹ ọrọ abẹle fun ijọba apapọ n dari.

To si fẹ ki ile ejọ tun pàṣẹ pe ki gbogbo awon ibudo igbeyawo ti ijọba apapọ da silẹ di titi pa.

Pẹlu idajọ yii, o se e se ki opin de ba ariyanjiyan to ma n waye lori iwe ẹri ibudo igbeyawo to nìyí julọ ni Naijiria.