Covid-19 vacine: Àjó NYSC kò ní fún àgùnbánirọ̀ tí kò bá tíì gbabẹ́rẹ́ covid-19 kò ní lánfààní láti wọ kámpù

Ni bayii, gbogbo agunbanirọ to n sinrulu ti ko ba gbabẹrẹ ajẹsara covid-19 ko ni lanfaani lati lọ si ipagọ ọlọsẹ mẹta NYSC.
Ọga agba ajọ NYSC, Shuaibu Ibrahim lo kede ọrọ yii lọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kejila ọdun yii.
Ọgbẹni Ibrahim ṣalaye pe eto yii yoo gberasọ lati ọsẹ diẹ si asiko yii tawọn agunbanirọ yoo tun lọ si ipagọ fun ọsẹ mẹta fun igbaradi.
- Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin Yinka Alaseyori àti Sola Allyson tí Alaseyori ń bẹ̀bẹ̀?
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pẹ̀lú omíjé kíkorò ...'
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ awakọ̀ tírélà tó gbá akẹ́kọ̀ọ́ mérìnlá nílùú Eko
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
- Wọ́n gé gògòńgò ìyá wa lọ lẹ́yìn tí wọ́n pa a- Omo Iya Deeper Life
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
Nigba ti o ba awọn agunbanirọ isọri ''C'' sọrọ, ọga agba NYSC ṣalaye awọn agunbanirọ gbọdọ ni ẹri to daju lati fihan pe wọn ti gbabẹrẹ ki wọn to le forukọ silẹ.
O ni ajọ NYSC n gbiyanju lati ri pe covid-19 ko maa ran kaakiri si pẹlu bi ẹda covid-19 Omicron ṣe n ṣọṣẹ lọwọ bayii ni Naijiria.
Ọga agba ajọ agunbanirọ tun sọ pe ko ni si isinmi fawọn agunbanirọ lẹyin ọsẹ meji ti wọn ba lo ni ipago ki wọn to lọ si ibi ti wọn ti maa sinrulu.
Bakan naa ni o rọ wọn lati yago fun irinajo alẹ, o ni ki wọn ma gunle irinajo to ba ti ju ago mẹfa irọlẹ lọ.
Ọgbẹni Ibrahim ni awọn agunbanirọ le sun ni bareke awọn sọja tabi ọfiisi ajọ NYSC nibi kibi ti ilẹ ba su ba wọn.
Ọga agba NYSC tun rọ awọn agunbanirọ lati wa iṣẹ ọwọ kan kọ tabi ni okowo kan ti wọn n ṣe dipo ki wọn kan joko ti iwe ẹri nikan lati wa iṣẹ ti ko wo pọ.












