Demilade Fadare: A jókò sí iwájú ilé àwọn Pásítọ̀ di ago mẹ́ta òru ká tó rí òkú ọmọ wa, Demilade tó ti gún un pa sínú "cooler"
Baba ati iya Demilade Fadare ti iroyin iku rẹ tan kaakiri lọsẹ to kọja ti ni dandan, idajọ ododo lawọn fẹ lori iku rẹ tori awọn ko mọ ohun tawọn tabi ọmọde ọmọ ọdun meje awọn ṣe fun awọn to pa a.
Baba Demilade, Oluwasola Fadare to n ṣiṣẹ ni ilu Eko ti ko si si nile lasiko ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ sọ fun BBC Yoruba pe lẹyin ti awn ti wa a kiri titi titi ti wọn ko ri i di ọjọ keji lawọn pada gbọ lati agọ ọlọpaa pe inu cooler nile aladugbo wọn ni wọn ti ri oku rẹ.
Iya Demilade, Adedoyin Fadare ranti bi o ṣe pariwo sita fun iranlọwọ nigba ti ko ri i ki Demilade tete pada sile lati ibi to ti ran an ko lọ ra ogi ti oun ati aburo rẹ yoo fi jẹ mọimọi ti iya wọn se.
"Iwaju ile awọn to pa a yii gan ni mo ti kọkọ figbe ta tori ile wa sunmọra gan, Demilade maa n pe wọn ni "Grandpa, grandma". Nnkan ti Pasitọ Olajiga sọ fun mi ni pe Ọlọrun yoo fun mi ri... Afigba ti mo gbọ lọjọ keji pe inu "cooler" Pasitọ ni wọn ti ba oku ọm mi (O sọkun kikoro).
Iya Demilade tilẹ sọ fun BBC Yoruba pe inu ọgba ti awọn ni awọn Pasitọ yii maa n gbe ọkọ wọn si ti wọn ba ti wa nile.
Ati iya ati Baba Demilade lo ni idajọ ni awọn fẹ lori ọrọ yii.

