Kudirat Soremi No Network: Tí mo bá jáde nígbà míì, àwọn èèyàn á ṣì máa kí mi bíi pé etí mi ò gbọ́rọ̀

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ eré bíi adití àti ojú táwọn olólùfẹ́ mi ma fi ń wò mí níta nìyìí - Madam No Network

"Tẹ́ẹ bá fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ sókè dáàdáà, ó yẹ kẹ́yin náà, ẹ̀ẹ́ ti máa gbọ́ ọ, kò sí Network o".

Kudirat Soremi jẹ gbajumọ oṣere Yoruba ti ọpọlọpọ mọ si "Madam No Network", o ṣalaye bo ṣe rin in toun naa darapọ mọ awọn oṣere ti Ọlọrun si ṣaamin si talẹnti rẹ eyi to n ta fun un bayii.

"Mi o ki n ṣe aditi, mo kan maa n ṣe bẹẹ ninu ere ni"

Kudirat ni o yẹ ki awọn eeyan maa mọ iyatọ laarin igbe aye oṣere loju aye ati bi wọn ṣe maa n ṣe lori itage ko ma baa si idarudapọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Madam No Network sọrọ nipa ibi to ba a de ninu iṣẹ Tiata ati bo ṣe wa di gbajugbaja bayii lati bii ogun ọdun to ti n ṣe ere.

Bakan naa lo tun sọ bi awọn eeyan ṣe maa n ṣe sii to ba jade ti wọn a maa kii ni iki ẹni ti ko gbọrọ.

Bo ṣe n darapọ mọ awọn ọdọ to jẹ oṣere lati ṣere papọ jẹ iyalẹnu fun awọn mii, gbogbo eyi ni oṣerebinrin to jẹ ọmọ ijẹbu ode yii ṣe alaye rẹ.

Bakan naa lo sọrọ lori idi to fi rẹ ara rẹ silẹ gẹgẹ bi agbalagba to n darapọ mọ awọn ọmọde laarin wọn ti wọn si jọ n ṣe e lai si wahala.