Lekan Odunare: Ìyàwó ọkùnrin tí fídìò ṣàfihàn bó sẹ pa ara rẹ̀ nínú odò ọ̀sà sọ nkan tó ṣeéṣe kó fàá

Lekan Odunare

Oríṣun àwòrán, Screeshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iyawo Lekan Odunare, ọmọkunrin to bẹ si odo ọsa nipinlẹ Eko, ti sọrọ lori nkan to ṣe e ṣe ko mu ọkọ rẹ gbẹmi ara rẹ.

Ọjọ Iṣẹgun to kọja ni Odunare bẹ sodo nijọba ibilẹ Epe, ti wọn si ri oku rẹ ni Ọjọbọ.

Rufiat Amusa sọ fun awọn akọroyin pe o ti to ọjọ diẹ ṣaaju iku Lekan, to ti n sọ pe oun yoo pa ara oun.

O ni ṣugbọn ko si ẹni to ka ọrọ rẹ si, ti gbogbo awọn to wa ni ayika rẹ si n sọ pe oogun oloro mimu lo jẹ ko ma a sọ iru ọrọ bẹẹ.

Iya ọlọmọ kan ọhun sọ ninu fidio kan ti BBC ri lori ayelujara The Punch, pe iyalẹnu lo pada jẹ fun awọn lati gbọ pe Olamilekan bẹ si odo.

"Lootọ lo ti n sọ tẹlẹ pe oun yoo pa ara oun, ṣugbọn ko si amojuto to peye fun. Ka ni wọn mojuto ni, ọrọ rẹ ko ba ma buru bayii".

"Ko si ẹni to ka ọrọ ẹnu rẹ si, oogun oloro 'Colorado' ni wọn ro pe o mu ko maa sọ isọkusọ. Nitori rẹ si ni wọn ko fi ṣe agbeyẹwo nkan to n sọ. Kii mu Colorado, amọ o ma n mu Arizona, botilẹ jẹ pe o ti pẹ to ti mu u kẹhin."

Rufiat to jẹ ọmọ ipinlẹ Oyo sọ pe nkan ti ọkọ oun tẹnumọ ko to o gbẹmi ara rẹ ni pe ki oun ma jẹ ki iya jẹ ọmọbinrin ti wọn bi.

Lọjọ ti Odunare bẹ si odo, fidio kan ṣafihan rẹ nibi to ti joko si ori irin to yi afara to wa lori odo naa, ti oju rẹ si kọrẹ lọwọ.

Ninu fidio naa, ọkunrin kan lo n ya fidio yii, to si n beere ibeere lọwọ Odunare nipa idi to fi joko sibẹ. Amọ, ko fun ni esi kankan. Lẹyin naa lo bẹ sinu odo.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post