Okùnrin tó jí àwọn olùjọ́sìn gbé ní ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìṣọ́ oru kó sọ́wọ́ Amotekun l'Ondo

Oríṣun àwòrán, @news360info
Ikọ alabo Amotekun ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu okunrin kan, Igbekele Abiodun, lori ẹsun pe oun atawọn ẹmẹwa rẹ kọlu ṣọọṣi kan lasiko iṣọ oru, to si ji awọn olujọsin mẹrin gbe nibẹ.
Adari ikọ naa, Adetunji Adeleye sọ pe Abiodun wa lara awọn afurasi márùndínlọ́gọ́rin ti ọwọ awọn tẹ kaakiri ipinlẹ ọhun lori oniruru ẹsun bii ijinigbe, idigunjale, eti bẹẹ bẹẹ lọ.
Lasiko ti wọn n fi oju awọn afurasi naa lede ni olu ileeṣẹ oAmotekun to wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akure, Adeleye sọ pe Abiodun atawọn ẹmẹwa rẹ ya bo ile ijọsin naa ni nnkan bii aago mọkanla alẹ, ti wọn si ji olujọsin mẹrin gbe lọ.
- DSS fún mi ní omi kẹ́míkà mu látìmọ́lé, mi ò gbádùn láti ìgbà náà, wọ́n lù mú gan an- Lady K
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
- Wàhálà n rúgbó bọ̀ ní ìlú kan ní India nítorí bí àwọn Musulumi ṣe n kírun
Gẹgẹ bii ohun to sọ, agbegbe Edo Lodge, ni ile ijọsin ọhun wa niluu Akure.
O ni "Ni nnkan bii ago mọkanla alẹ ni a gba ipe pajawiri kan pe awọn kọlọrọsi kan ti ji awọn olujọsin gbe lọ ninu ṣọọṣi wọn."
"Abiodun yii gan lo kọkọ wọle sinu ṣọọṣi naa, to si ni ki awọn ọmọ ijọ dideduro, ki awọn ẹmẹwa rẹ to ku to wọle, wọn ji ọmọ ijọ mẹrin gbe lara wọn, wọn si ṣe awọn eeyan naa baṣubaṣu."
Adeleye sọ siwaju si pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni awọn bẹrẹ si n tọpasẹ awọn afurasi ọhun.
Lẹyinorẹyin, wọn ri ẹnikan mu lara awọn ajinigbe naa, wọn si doola awọn eeyan mẹrin ti wọn ti ji gbe ṣaaju.
O ni "Lẹyin ti a bẹrẹ si n tọpinpin wọn, a ri ẹnikan mu lara wọn, ṣugbọn a ṣi n wa awọn akẹgbẹ rẹ to ti na papa bora."
"A ti ko awọn ti wọn ji gbe naa wa si ọọfisi wa, wọn si ti gba itọju."
Adeleye pari ọrọ rẹ pe inu igbo kan ni ipinlẹ Ekiti ni awọn ti mu afurasi naa ni nnkan bii aago kan abọ oru, ati pe niṣe lo mura bii obinrin lasiko ti wọn mu."
Ọkan lara awọn ti wọn jig be ọhun, arabinrin Eunice Taiwo sọ pe awọn ajinigbe naa gba owo ati ẹrọ ilewọ oun.












