Muslim prayers: Wàhálà n rúgbó bọ̀ ní ìlú kan ní India nítorí bí àwọn Musulumi ṣe n kírun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Rogbodiyan kan ti n waye agbegbe kan nitosi ilu Delhi, to jẹ olu ilu orilẹ-ede India, nitori bi àwọn kan ṣe koju ija si awon musulumi.
Lati bi oṣù mẹta, gbogbo ọjọ Ẹti ni àwọn kan to jẹ ẹlẹ́sìn Hindu ma n ko ara wọn jọ lati di ìrun kiki awọn musulumi duro ni àwọn ibi to jẹ ilẹ̀ ijọba ni ilu Gurgaon.
Wọn a si ma a pariwo pe ki wọn o fi opin si irun kiki ni àwọn àyè bi ibudokọ, àwọn ilẹ̀ ijoba to wa nitosi àwọn ileesẹ nla, ọjà ati laarin adugbo ti àwọn eeyan n gbe. Àwọn ibi ti a darukọ yii ni awon musulumi to n sisẹ nibẹ ti ma n kirun lati àìmọye ọdun.
- Sunday Igboho: Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Igboho tó ká sórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Kìí ṣe Tinubu ló kọ́ ilé tí mò ń gbé fún mi, GTB ló yá mi lówó tí mo fi parí ilé náà - Ayo Adebanjo
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ tí ọwọ́ àjọ DSS tẹ èèyàn 30 lára wọn
- Adeoye Fawaz rèé ''Conductor'' ọmọ abẹ́ ''Bridge Oshodi'' tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi eré Chess
Nise ni àwọn ẹlẹ́sìn Hindu naa ma n fi ọkọ wọn di oju ọna, ti wọn si ma n pariwo le awọn musulumi naa lori pe alakatakiti ẹsin ni wọn.
Ẹnikan lara awọn olori àwọn Hindu to n fi ẹhonu han, Kulbhushan Bhardwaj sọ pe awọn ko tako ẹsin Islam, sugbọn bi wọn ṣe n gbadura ni gbangba jẹ "Jihad ilẹ̀ gbígbà".
Àmọ́, àwọn musulumi sọ pe aisi àyè tó pọ̀ lo n faa.
Ọdun 2018 ni iwọde ti bẹrẹ nitori adura gbigba ni gbangba. Leyin ọpọlọpọ iduna-dura, àwọn ẹgbẹ́ musulumi gbà lati din àwọn ibudo ti wọn lo ku si mẹtadinlogoji lati mejidinlaadọfa.
Ṣugbọn iwọde tun bẹrẹ pada ni ọdun yii, ti ẹnikẹni ko si le sọ nkan to fa. Leyin naa ni àwọn musulumi tun din ibudo ti wọn ti n kirun kù si ogún.
Ni bayii, nise ni àwọn ọlọpaa ma n yi àwọn musulumi naa ka lasiko ti wọn ba n kirun.












