King of Satan: Mọ̀ si nípa Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kí ó tó jáde láyé

Alagba Simon Simon Odo, ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Ọba Satani , (King of Satan) ti jade pipo.
Alagba Odo fẹ iyawo mẹtadinlọgọta, 57 ki o to jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọrin, 74.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2021 ni alagba naa jade laye.
- 'Àìsàn ibà tí mo kó ní Nàìjíríà ló mú kí wọ́n gé ẹsẹ̀ mi méjèjì àmọ́ mi ò kábàámọ̀'
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Imo
- Adeoye Fawaz rèé ''Conductor'' ọmọ abẹ́ ''Bridge Oshodi'' tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi eré Chess
- Ìròyìn òfegè lásán ni! Ilé ẹjọ́ kò gba agbára lọ́wọ́ àwọn ibùdó ìgbéyàwó tí a dá sílẹ̀, ẹ m'ẹ́nu kúró lórí Ikoyi Registry
- Mo ṣèlérí láti lọ gbà'mọ̀ràn gidi kí n tó ṣe ìpinu dídupò ààrẹ ní 2023
- Orílẹ̀èdè UK yọ orúkọ orílẹ̀èdè 11 kúrò lábẹ́ òfin tó de arìnrìnàjò wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Ìyàwó Cute Abiola sọ̀rọ̀ lórí ìrirí ọkọ rẹ̀ ní àhámọ́ iléeṣẹ́ ọmogun orí omi
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó dáná sún akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì Osun, ohun táá ṣe nìyìí - Àláṣẹ iléèwé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkọ ìyàwó tó pa ìyàwò rẹ̀ nítorí ogún tó ní
Ọmọbinrin baba naa, Uchenna Odo lo fi to BBC leti pe nnkan bii agogo mẹta owurọ ni baba oun jade laye lẹyin aisan ranpẹ. Ilu Aji, ni ijọba ibilẹ Igbo-Eze North nipinlẹ Enugu ni wọn bii si.
Tani ni Ọba awọn Satani yii gan an?
Alagba Odo ṣalaye fun BBC pe oun paapaa ko mọ ni pato iye ọmọ ti oun atawọn iyawo oun bi.
Gbajumọ oniṣegun ibilẹ ni nigba aye rẹ ti awọn eeyan si mọọ gẹgẹ bi ọba Satani.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC Igbo ko to jade laye, Alagba Simon Odo ṣalaye pe " emi gangan ni ọba Satani. Bi o ba gba mi leti emi naa a gba temi"
O ni ilu iya oun loun ti kọ ohun ti oun n ṣe.
Inu ijọ Katoliki ni wọn bi alagba Odo si, kii ṣe isegun ibilẹ lo bẹrẹ aye rẹ pẹlu.
" Ni ọdun 1956 ni wọn ṣe iribọmi fun mi mo si ṣe igbọwọle ni ọdun 1958, mo ṣiṣẹ isin katoliiki lati ọdun 1959 si 1960."
Ki lo sọ ọ di Oniṣegun ibilẹ?
Fun ọdun marun lo ni oun fi ba ikọ fehe (Tuberculosis) finra ti oun si gbagbọ pe wọn fi ṣe oun nigba naa ni.
Lẹyin eyi lo ni oun tun dubulẹ aisan miran.
"Lati ori ikọ fehe ọdun marun yii ni wọn tun ti ṣe ogun simi, mo wa yarọ fun ọdun marun"
Gbogbo aisan yii lo mu ki alagba Simon Odo di ero ilu Ijẹbu nibi to ni oun ti wa ṣe awari rẹ pe eeyan lo wa nidi ọrọ oun kii ṣe aisan latọwọ Ọlọrun.
Ilu Ijẹbu Ode lo wa fun ọdun meje ki o to pada si ilu rẹ lati lọ maa ṣe iwosan fun awọn eeyan
O ni agbara ti oun ni ko si fun pipa eeyan rara.
O ni, " bi eeyan ba mu ọdunrun miliọnu dọla wa pe ki ki n pa eeyan tabi fun oun ni majele lati pa ẹnikẹni, maa sọ fun iru ẹni bẹẹ pe ko le ṣeeṣe. Ọjọ ti mo ba ṣe e ni maa ku"












