UK Omicron Nigeria Ban: Orílẹ̀èdè UK yọ orúkọ orílẹ̀èdè 11 kúrò lábẹ́ òfin tó de arìnrìnàjò wọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Oríṣun àwòrán, @BayoOmoboriowo
Ijọba orilẹede Gẹẹsi ti sọ pe oun ti yọ orukọ awọn orilẹede mokanla to wa ninu iwe awọn ti wọn fofin de pe ko gbọdọ si arinrinajo ti yo wọle lati ibẹ si ilẹ Gẹẹsi.
Asẹ naa fidi rẹ mulẹ pe bẹrẹ lati agogo mẹrin owurọ ọjọru, ko si idiwọ fun gbogbo awọn arinrinajo lati Angola, Botswana, , Lesotho, Malawi, Mozambique, Namibia, Nigeria, South Africa, Zambia ati Zimbabwe to fẹ wa si orilẹede UK mọ.
Ni oṣu kọkanla ni aṣẹ yii pada si ifidimulẹ gẹgẹ bi ara igbesẹ igi gogoro ma gun mi loju eyi ti ijọba ilẹ Gẹẹsi gbe lati dena ọwọja ẹda arun Coronavirus, Omicron.
- Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Imo
- Ìròyìn òfegè lásán ni! Ilé ẹjọ́ kò gba agbára lọ́wọ́ àwọn ibùdó ìgbéyàwó tí a dá sílẹ̀, ẹ m'ẹ́nu kúró lórí Ikoyi Registry
- Adeoye Fawaz rèé ''Conductor'' ọmọ abẹ́ ''Bridge Oshodi'' tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi eré Chess
- Mo ṣèlérí láti lọ gbà'mọ̀ràn gidi kí n tó ṣe ìpinu dídupò ààrẹ ní 2023
Amoṣa, minisita feto ilera nibẹ ti ṣalaye pe eda arun naa ti tan kalẹ kaakiri to bẹẹ gẹ ti ko fi si iwulofu aṣẹ yii mọ.
O ṣalaye fun ile asofin apapọ orilẹede naa pe "nibayii arun naa n tan kaakiri agbegbe gbogbo lorilẹede UK ati kaakiri agbaye."
Amoṣa, O ni "ilana ayẹwo ti won gbe kalẹ fawọn arinrinajo lati ilẹ okeere yoo si wa nilẹ."
Gbogbo awọn eeyan to ba wọ ilẹ Gẹẹsi lati awọn orilẹede to wa ninu iwe orukọ awọn orilẹede makan ti awon alaṣẹ UK gbe kalẹ nitori ajakalẹ ẹda arun tuntun naa ni wọn n funrawọn dan owo ile itura ti ijọba fọwọsi ti wọn n fi wọn wọ si fun igbele ọlọjọ mẹwaa.
Nibayii ti wọn ti yọ orukọ awọn orilẹede naa kuro, wọn tun ti fidi rẹ mulẹ pe awọn to wa ni igbele yoo lanfani lati maa tete lọ sile ju ti atẹyinwa lọ ṣugbọn"ki wọn maa tẹle awọn ofin ti wa nilẹ bi awọn ti de latawon orilẹede ti wọn ko fi ofin de tẹlẹ."
Awọn arinrinajo kan tu san ẹgbẹlẹgbẹ owo Pọun ilẹ Gẹẹsi lati lee duro lawọn ile itura ti ijọba fọwọsi fun igbele ti wọn ko si yee n sọrọ lori aukunoju iwọn eto ti wọn gbe kalẹ nibẹ pẹlu awọn ounjẹ ti ko ba ara mu ti wọn n fun wọn nibẹ.
Amọ ooliri agbegbe Lan aster, Stephen Barclay ṣalaye fun ile asofin kekere lorilẹede naa.
Eredi fifi aṣẹ de awọn orilẹede ka oe awọn arinrinajo ko gbọdọ gba ibẹ wọ orulẹede UK ko yẹ lori wiwa ọna lati gbegbe igbesẹ kiakia lati dẹkun itankalẹ ẹda arun Coronavirus Omicron.
Amoṣa bayii, o ti wulẹ tan wọg ogbo ileto, bẹẹni ijoba ko si lero pe kiko awọn arinrinajo lati iwọnba orilẹede kan si igbele lawọn ile itura tun ba mọ.
Iroyin ayọ leyi yoo si jẹ fun awọn ro n gbero ati wa sorilẹede UK lati awọn orilẹede bii South Africa ati Nigeria, tabi awọn to ti sun dide wọn lati awọn orilẹede wonyii si ẹyin.
Amọ o, ko ni rọrun fun awọn to ko sinu jankariwọ agbedide aṣẹ naa ni ọsẹ meji sẹyin lẹyin ti wọn ti san owo fun hotẹli ti wọn yoo ti ṣe igbele wọn ti wọn si n reti ki ijọba san owo naa pada.
Awọn ileeṣẹ lẹka Irinajo pẹlu n fẹ ki ijọba fopin si gbogbo ofin ide a gbogbo. Wọn fi oju wo awọn igbesẹ ayẹwo ti ijọba n gbe gẹgẹbi eyi to n bomi pa ina idagbasoke wọn ṣugbọn ko daju boya ijọba ṣetan lati ṣe gbogbo eyi.
Gbogbo awọn ileeṣẹ irinajo afẹ to maa n jere gọbọi lasiko yii latara awọn to n sanwo irinajo lati isinmi bẹrẹ lati nnkan bii opin oṣu ati ibẹrẹ oṣu kini li ti n kọminu bayii.
Igbesẹ ijọba orilẹede UK naa faọpọ ifapajanu lat'ọdọ awọn orilẹede ilẹ Afirika, ti ajọ iṣọkan agbaye, UN si tun tọka si igbesẹ naa gẹgẹ idẹyẹsi ẹlẹyamẹya.
Lọwọ ti a wa yii, gbogbo awọn to ba n rinrinajo wọ ilẹ Gẹẹsi lo gbọdọ ṣe ayẹwo Kokoro arun COVID-19 ti jijade esi rẹ ko si kọja wakati mejidinlaadọta si asiko Irinajo rẹ lọ.
Ọpọlọpọ lo si ti wa n woye bayii pe niwọn igba ti wọn ti gbe aṣẹ to de wiwọle awọn arinrinajo latawon orilẹede naa ti si ẹgbẹ kan, ki lo tun fa ayẹwo oni tipatipa atawọn ofin idena miran?
Minisita fun igbokegbodo ọkọ Grant Shapps ṣalaye pe wọn yoo tun awọn ofin to de ṣiṣe ayẹwo fun Kokoro arun Coronavirus naa yẹwo lọsẹ kini oṣu to n bọ.
Ọgbẹnu Shapps tun sọọ siwaju loju opo Twitter pe, "Gẹgẹbi iṣe wa, gbogbo ofin to de irinajo la n gbe yẹwọ loorekoore, bẹẹni a lee gbe aṣẹ tuntun jade lori wọn pẹlu bi o ba nilo ki a ṣe bẹẹ lati daabo bo araalu"
A kò ní torí ihàlẹ́ Nàìjíríà yí òfin má wọ ìlú wa táa gbé lé wọ́n lórí padà - Ìjọba UK
Fa ki n fa lori ọrọ ofin ma wọle ti ilẹ Gẹẹsi gbe le Naijiria atawọn orilẹede mii lori titun gba ọna miran yọ bayi paapaa fun Naijiria.
Tuntun taa tun gbọ ni pe aṣoju ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria ti sọ pe awọn ko ni sẹ nitori ihalẹ ti Naijiria ha mọ awọn lori ọrọ naa.
Ninu idahun kan to jade lọjọ Aiku lati ọwọ agbẹnusọ aṣoju Dean Hurlock si ibeere ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch, o ni digbi lawọn yoo duro lori ofin to wa nilẹ.
- BBC Africa Eye tú aṣírí ẹgbẹ òkùnkùn Black Axe ní Nàìjìríà, ìpànìyàn àti àwọn olóṣèlú tó wà lẹ́yìn wọn
- Ìgbésẹ̀ láti dínà arìnrìnàjò ọmọ Nàìjíríà sí UK yóò da ètò rú fáwọn tó fẹ́ bá ẹbí wọn ṣe Kérésìmesì ní UK
- 'Omicron ti wọ Nàìjíríà o', ìjọba àpapọ̀ kéde; Canada bẹ́gi dínà àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ wọlé
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
Esi yi jẹ idahun lori igbesẹ ti Minisita feto irina Naijiria Hadi Sirika lawọn fẹ gbe lati fi gbẹsan nkan ti ilẹ Gẹẹsi ṣe.
Lọjọ Kẹfa oṣu Kejila ọdun yi ni ileeṣẹ aṣoju ilẹ Gẹẹsi fi atẹjade sita pe awọn yoo fi Naijiria kun awọn orileede ti wọn fofin de nitori awọn to ko ẹda Covid-19 Omicron tuntun.
Ẹwẹ, Minisita feto ilera keji Adeleke Olorunnimbe Mamora ti sọ pe awọn ko gbe igbesẹ lati fofin de ọkọ baalu lati ilẹ Gẹẹsi nitori pe awọn fẹ gbẹsan.

Oríṣun àwòrán, Twitter/CatrionaLaing1
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lori ileeṣẹ amounmaworan Channels, Mamora tan imọlẹ si awuyewuye to n lọ lọwọ yi.
O ni Naijiria ko gbe igbesẹ yi lati fi gbẹsan bi kii ṣe pe awọn ṣe tori ohun ti yoo ṣe anfaani fun ilẹ naa.
''Mi o fẹ ki ẹ foju wipe a fẹ gbẹsan wo ọrọ yi. Ko ri bẹẹ rara''.
''Bi awọn orileede ba n dunadura laarin ara wọn,mo mọ pe wn a maa ṣe gbafu mi ki n gba fun ẹ laarin wọn.Amọ ohun taa ṣe ni pe a wo nkan ti yoo mu anfaani ba Naijiria ninu ọrọ yi ni''
Lọwọlọwọ bayii, Naijiria ati orileede UAE n jijọ ba arawọn fa lori gbigbegi dina irina baalu laarin orileede mejeeji .
Minisita feto irinajo ofurufu Naijiria sọ pe awọn kan ni gba ki baalu lati UAE wọ Naijiria nitori UAE naa gbegi dina awọn baalu Naijiria to fẹ fo lọ sibẹ.















