Omicron variant: Ìjọba Naijria ní kò sí ẹ̀ní tó ní ẹ̀dà covid-19 tuntun Omicron Variant ní Naijiria

Orilẹede Canada ti fi ofin sita bayii pe Naijiria ti wa lara awọn orilẹede ti ko gbudọ rinrinajo wa si Canada.
Nibayii, Canada ti fi orilẹede Naijira, Malawi ati Egypti kun orukọ awọn orilẹede ti wọn o fẹ ko rinrinajo wa si orilẹede wọn.
Eyi n waye laarin gbogbo awuyewuye pe ẹda Aarun Covid-19 tuntun mii, Omicron tun ti gba aye kan.
Canada ṣe ikede yii lọjọ Ẹti to kọja ti wọn si ni awọn yoo ṣe ikede ilana aatle to ku bo ba ẹ nlọ.
Bakan naa ni Minista ilẹ Canada nipa aabo ilu, Marco Mendicino naa ti sọ pe oun ko ni ọrọ kankan lati sọ gẹgẹ bi esi si igbesẹ awọn lori ibode.
Ipinlẹ Eko ni Naijiria ni ilu nla ekeji to n gbayun ju lagbaye gẹgẹ bi akọsilẹ fun ọdun 2021 ti ajọ Economic Intelligence Unit (EIU) fi sita.Ẹwẹ, ajọ to n ri si imojuto aisan pajawiri ni Naijiria, NCDC naa ti fi ọrọ sita bayii pe wọn ti ri eeyan mẹ́ta to ni Omicron ni Naijiria.
Ṣaaju, Ìjọba Naijria ní kò sí ẹ̀ní tó ní ẹ̀dà covid-19 tuntun Omicron Variant ní Naijiria
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti tun fi idi rẹ mulẹ pe o da awọn loju pe ko i tii si ẹda arun Covid 19 tuntun, Omicron Variant ni Naijiria.
Eyi ko sẹyin bi orilẹede Canada ṣe kede pe awọn ọmọ Naijiria meji to wọle si ilẹ wọn ni arun Covid -19 tuntun naa.
Amọ, Alaga igbimọ to n ṣeranwọ fun aarẹ Buhari lori idena ajakalẹ arun, Ifedayo Adetifa ni ko si ọrọ ariyanjiyan nibẹ.
- BBC Africa Eye: Ìwádìí tú àṣírí bí ààrẹ orílẹ̀-èdè DR Congo ṣé lú owó aráàlú ní pónpó
- Wo ọ̀nà táwọn olólúfẹ́ Baba Suwe ní London àti Manchester fẹ́ gbà ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fun
- Timothy Adegoke: Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jọ́ lórí ikú àbúrò mi ni Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì rán lawyer kó gbé owó wá - Ẹ̀gbọ́n Timothy
- Ọ̀nà ẹ̀bùrú ni àwọn tó ni ọkọ̀ òfúrufú tí a gbẹ́sẹ̀lé gbà kó wọn wọ Naijiria – Iléeṣẹ́ Custom
- Ọ̀sere tíátà kan rí ẹ̀bùn owó ₦8m gbà
Adetifa ni ko si idi fun awọn ọmọ Naijiria lati ma a ṣe iyemeji lori boya ẹda tuntun naa wa ni Naijiria abi bẹẹ̀ kọ.
Ohun ti a mọ ni pe lọwọlọwọ bayii ko i tii si ẹnikẹni to farahan pẹlu ajakalẹ arun naa.
''Amọ a ni awọn ti a ṣẹṣẹ ṣe ayẹwọ fun ti esi wọn yoo si jade ni aipẹ.''

''Bio tilẹ jẹpe a ko fi aake kọri ko le e si ni Naijiria, amọ pe nkan le yipada, amọ ni ọwọ yii ko i tii si''
Minisita fun ọrọ ilera, Osagie Ehanire ni awọn alaṣẹ n foju silẹ lati wo bii o ṣe n lọ lori ẹda tuntun Covid -19 naa.
Ẹda tuntun, Omicron Variant naa ni wọn kọkọ ri ni orilẹede South-Africa, amọ wọn ko i tii fi idi rẹ mulẹ iru ijamba to le e ṣe fun awujọ eniyan.
- "Ààbò ọgbà ẹ̀wọ̀n Jos lágbára, kàyéèfì ní bí agbébọn ṣe kọ lù ú"
- Àwọn àjòjì ṣá obìnrin tó ń lọ gbálẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Deeper Life pa, ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ara rẹ̀
- Abiyamọ, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn kan bá ìbúgbàmù ọkọ́ aképo lọ́ ní Lafenwa
- Wo ọ̀ná tí àwọn ọkùnrin lè gbà ṣe ìfètòsọ́mọbíbí láì lo kọ́ndọ́ọ̀mù lásìkò ìbálòpọ̀
- Mí ò polongo ìdupo ààrẹ ọdún 2023 fún Tinubu-Foluke Daramola
- Àwọn agbébọn tó yabo ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Jos há síbẹ̀ lẹ́yìn tí agbófinró yí wọn ká
- Kí ló yẹ kóo sáré ṣe bí ejò bá ṣá ọ jẹ?
- Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ yìí tí wọ́n bá okú wọn ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn
Ọjọ Isinmi ni orilẹede Canada kede pe ẹni meji to ni arun naa lorilẹede wọn wa lati orilẹede Naijiria.
Amọ ijọba Naijiria ni awọn n reti ẹkunrẹrẹ iroyin lati ọdọ ilẹ Canada nitori ko si ọkọ baalu taara lati orilẹede Naijiria si Canada.
Kéére o! Wọ́n ti rí èèyàn méjì tó ní ẹ̀yà Covid-19 tuntun, "Omicron variant" nínú báàlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dipo ki wọn gba igboriyin ohun sadankat, orilẹede South Africa ti gba ibawi lori pe awọn ni wọn ṣawari ẹya Covid-19 tuntun.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn orilẹede agbaye fi ọrọ yii lede gẹgẹ bi awọn orilẹede agbaye ṣe tun bẹrẹ si ni bẹgi dina irinajo wọ orilẹede wọn lati South Afirica tori ajakalẹ arun naa ti n gbilẹ sii.
Ajọ eleto ilera agbaye, WHO ti ni ajakalẹ tuntun yii, Omicron jẹ eyi to n kọ ni lominu ti wọn si ni ifarahan rẹ yii ni anfani ati ran mọ ẹlomiran kia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibayii, wọn ti ri awọn to ko arun naa ni ilẹ Yuroopu - meji ni Uk, meji ni Germany, ọkan ni Belgium, ẹyọkan miiran ti wa ni Italy nigba ti wọn tun fura pe wọn ri ọkan ni Czech Republic.
Orilẹede Israel ti wọn ti ni aridaju pe Omicron wa ti pinu lati bẹgi dina gbogbo arinrinajo lati ma wọ ilu wọn lati alẹ ọjọ Aiku.
Bakan naa, wọn ti kẹfin ikọlu Omicron ni Botswana ati Hong Kong naa.
Ṣe ni orilẹede Netherlands bẹrẹ si ni ṣe ayẹwo fun gbogbo ẹni ba wọle lati South Africa boya wọn ti ni Omicron tabi wọn ko nii.
Wọn rii pe eeyan meji to wa lori ọkọ ofurufu KLM lo ni Covid-19 ti wọn si ti sọ wọn si ibudo ifarapamọ to wa nile itura kan ni papakọ ofurufu Amsterdam nibi ti wọn ti tẹsiwaju aywo fun wọn.
Ẹda Omicron variant ti wọn kọkọ ri jade ninu akọsilẹ ajọ WHO waye lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun 2021.
Ẹwẹ, ninu ọrọ kan ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okere ni South Africa fi sita, wọn bu ẹnu atẹ lu bibẹgi dina irianjo awọn eeyan.
Wọn ni "iwadi ijinlẹ Sayẹnisi yẹ ko gba igboriyin ni kii ṣe ijiya".
Netherlands ti n ba kikoju ajakalẹ arun tuntun yii faa ti wọnn si ti fẹ paṣẹ isede tipa-tipa lalẹ ọjọ Aiku.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn woye pe didena irinajo jẹ bi ijiya fun South Africa tori pe wọn tete ṣawari arun tuntun yii ṣaaju ẹnikẹni ti wọn si ni eyi yatọ si bi wọn ṣe maa n kọ iha si orilẹede mii to ba jẹ ibẹ ni wọn ti ṣawari ajakalẹ arun.
Oṣiṣẹ ajọ isọkan ilẹ Afirika kan sọ fun BBC pe awọn orilẹede to ṣẹ n dagba lo yẹ ki wọn da ẹbi yii ru tori eyi ṣẹlẹ nitori pe agbaye kuna lati jara mọ gbigba abẹrẹ ajẹsara.
















