Akure Murder: Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ yìí tí wọ́n bá okú wọn ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn

Akure Murder: Àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn olólùfẹ́ tí wọn bá okú wọn ni ilé ìgbọ̀nsẹ̀ wọn

Oríṣun àwòrán, PunchNewspaper

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ikú tó pa àwọn ènìyàn mẹ́ta kan tí okú wọ́n sì ti ń jẹrà ki wọ́n tó ri wọ́n ni yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ nínú ilé wọn n'ilú Akure.

Lára òkú àwọn mẹ́ta náà nii à ti ri àwọn olólùfẹ́ méjì kan, Ojo Akinro àti Mary Igwe pẹ̀lú ọ̀rẹ́ wọn Lamidi Sherrif ni wọ́n bá nínú ilé wọn ni agbegbe Aralusi Kọtas ni Akure.

Gẹ́gẹ́ bi àwọn tó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà, wọ́n ni inú yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọ́n ti bá okú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí o si le túmọ̀ sí pé, àwọn ẹni àìmọ̀ kan lo pa wọn.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole

Ẹni náà ṣàlàyé pé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ti àwọn ko ri wọn, ara ẹbi àwọn olóògbé náà kò lélẹ̀ mọ́, bi wọ́n sì ṣe ń pe aago wọn, ó kàn ń dún ni kò sí ẹni ti ó gbé e.

Ẹni náà fi kun un pé, " nígbà tí kò sí ìdáhùn sí àwọn ìpè yìí ní àwọn ẹbi wọn gbà láti wá wọn lọ sí ilé tí wọn sì ríi pé wọ́n ti tí ilẹ̀kùn wọn pa láti ìta, wọ́n já ilẹ̀kùn náà láti wọlé.

"Lẹ́yìn tí wọ́n tú gbogbo àwọn yàrá ni wọ́n padà rí okú wọn nínú yàrá ìgbọ̀nsẹ ni bi ti wn kó wọn dà sí, àsìkò yìí ni wọ́n kíbòsí sí àwọn ara àdúgbò"

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmi Odunlai tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ ṣàlàyé pé, ẹ̀jọ̀ ìpànìyàn ni, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀.