Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ IOO sọ pé nítorí kí DSS má bà san N20b ni wọ́n ṣe n parọ́ gbígbé Igboho wá sílé

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, oyo reporters

Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Yoruba Nation, Ilana Omo Oodua, IOO, ti koro oju si igbesẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati gba Sunday Adeyemo Igboho kuro ni orilẹ-ede Benin Republic wa si Naijiria.

Ọjọ Iṣẹgun ni ajọ DSS sọ nile ẹjọ kan nilu Ibadan pe eto ti n lọ lati gbe Igboho wa sile.

Ẹgbẹ IOO sọ pe ọna lati ma san ogun biliọnu Naira ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki ajọ naa san fun Sunday Igboho ni wọn n wa.

Saaju ni ile ẹjọ giga nilu Ibadan sọ pe ki ajọ naa san owo ọhun nitori bi wọn ṣe kọlu ile Igboho lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021.

Nibi eto ifilọlẹ igbimọ agbaagba ẹgbẹ IOO to waye nilu Ibadan ni Ọjọru, ni ẹni to jẹ agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Maxwell Adeleye ti sọ pe irọ ni ọrọ ajọ DSS pe ijọba Naijiria ti n ṣeto lati gbe Sunday Igboho pada si Naijiria.

O ni "Wọn o ni owo lati san owo itanran naa, nitori naa ni wọn si ṣe fẹ ẹ doju idajọ bolẹ."

Ọgbẹni Adeleye sọ pe bakan naa ni ile ẹjọ ko ti i gba ẹbẹ ajọ DSS to fi n beere fun didun sisan owo naa siwaju.

Nigba ti oun naa n sọrọ, olori ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ pe igbesẹ to kan fun idasilẹ Yoruba Nation ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba, baalẹ ati awọn miran to tun ṣe koko.

O ni lootọ ni awọn ọdọ wulo ninu ijijagbara naa, ṣugbọn awọn nkankan wa to jẹ agbalagba lo le yanju rẹ.

Nitori naa si ni ẹgbẹ IOO ṣe da igbimọ agbaagba silẹ, eyi ti wọn kede Alhaji Alli Oyedeji gẹgẹ bi alaga fun.

Alhaji Oyedeji sọ fun awọn akọroyin pe igbimọ naa yoo ṣiṣẹ karakara lati rọ awọn eniyan pataki nilẹ Yoruba pe ki wọn o darapọ mọ gbigba ogo Yoruba pada.