FG names bandits terrorists: Ṣé ẹ ti gbọ́ nkan ti Sheikh Gumi sọ nipa ikéde àwọn jàndùkú gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí

Aworan Sheikh Gumi

Oríṣun àwòrán, Ahmed Gumi

Gbajugbaja onimọ ẹsin Islam ni Naijiria nii Sheikh Gumi ti fesi si igbesẹ ijọba apapọ lati kede awọn janduku gẹgẹ bii agbesunmọmi.

Sheikh Gumi ti kii ṣẹnuku lori ọrọ awọn janduku darandaran to n da araalu laamu sọ pe igbesẹ yi ko ni so eso rere.

Agbẹnusọ Gumi Hassan Salisu lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan.

O ni lootọ ni Sheikh naa sọ ninu atẹjade kan to wa nita pe'' ijọba apapọ tẹti si ọrọ apa kan lorileede Naijiria ni ati pe ko le ni so eso rere kankan''

Gumi tẹsiwaju pe ''wọn gbe igbesẹ lati kede awọn janduku darandaran gẹgẹ bi agbesunmọmi nitori ọrọ oṣelu ni''

''Ko ni anfaani kankan nitori ṣaaju ki wọn to kede wọn gẹgẹ bi agbesunmọmi, ijọba n doju ija kọ wọn bi igba pe agbesunmọ ni wọn''

O ni orukọ lasan ni wn yipada lati maa pe wọn tori naa oun ko ro pe o le yi nkan to wa nilẹ pada.

Ọrọ Gumi n waye lẹyin ọjọ meloo kan ti ile ẹjọ giga kan ni Abuja fọwọ si iwe ti ijọba apapọ k sile ẹjọ lati kede awọn janduku darandaran ni agbesunmọmi.

Ninu idajọ naa ti adajọ Taiwo Taiwo fi lelẹ lọjọ Ketadinlọgbọn oṣu Kọkanla, o ni iṣeṣi awọn ẹgbẹ janduku Yan Bindiga ati Yan Ta'adda j ti awọn agbesunmọmi.

Gumi wa sọ pe afiwe ikede yi dabi eleyi to waye nigba ti ijọba apapọ kede ẹgbẹ IPOB gẹgẹ bi agbesunmọmi.

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

''Bi ẹ ba ranti ikede IPO gẹgẹ bi agbesunmọmi, koda wọn fi aṣẹ ile ẹjọ gbe lẹyin.Amọ awọn orileede agbaye miran ko faramọ ikede yi tori naa o kuna lati ṣe iṣẹ to yẹ''

Ni idahun si ọrọ to n lọ yi, Minisita feto idajọ ni Naijiria Abubakar Malami lẹyin ti ile ẹjọ gbe ikede yi jade sọ pe afihan ifarajin ijọba lati koju awn janduku lo mu kawọn tọ ile ẹjọ lọ.

Ọfisi Malami lo kọ iwe sile ẹjọ lati gbe igbesẹ kikede awọn janduku yi gẹgẹ bi agbesunmọmi.

Lakotan, Gumi loun lero pe ikede yi ko wa ni fun awọn eeyan laaye lati maa foju agbesunmọmi wo gbogbo darandaran .