Sheikh Gumi builds school for herders: ìdí tí Gumi gi kọ́ ilé ẹ̀kọ́ fáwọn Fulani Darandaran rèé

Oríṣun àwòrán, Gumi/Facebook
- Author, Yetunde Olugbenga
- Role, Senior Broadcast Journalist
Apẹ̀tù saawọ laarin awọn ajinigbe atawọn araalu to tun ma ń gba awọn àgbè-sùnmọ̀mí àtàwọn agbebọn, ajinigbepawo nimọran, Sheikh Gumi sọ pé àwọn agbebọn setan lati da nkan ija ọwọ wọn silẹ bí ijọba ba tilẹ̀ le pèsè eto ẹ̀kọ́ àtàwọn nkan irọrun mii fáwọn Fulani Darandaran ni iha Ariwa ati jakejado Naijiria.
Gumi ṣipaya èyí lásìkò to ṣe ibẹwo si ibudo Sheikh Uthman Bin Fodio, eyi tii ilé-ẹ̀kọ́ ti àjọ Sheikh Gumi Mosque Foundation Limited kọ si inu igbo ìjẹko maalu, Kagarko Grazing Reserve to wa ni ẹbaa abule Kohoto.
Ẹni to ṣe agbekalẹ ile ẹ̀kọ́ náà ni Aafa Gumi.
Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, bi wọn ba leè kọ iru ibudo yii ti wọn ṣe lati maa kọ awọn Darandaran lẹkọọ kaakiri gbogbo ibi orileede Naijiria, awọn ọmọ Naijiria yoo wa lalafia.
Gumi ni dipo ki wọn maa na ọpọlọpọ bilionu lori awọn ológun lati ba awọn agbebon ja, kí Naijiria na iru owo bẹẹ lorii kíkọ ilé-ẹ̀kọ́ àti lori awọn olukọni.
Bákan naa lo ṣi aṣọ loju ọrọ pé òun ti bá awọn agbebọn sọ̀rọ̀ wọn si ni ifẹ lati ko gbogbo nkan ijagun silẹ kí wọn si gba alafia láyé be wọn ba leè rí ipese eto ẹ̀kọ́ àtàwọn ohun amayedẹrun mii fun awọn ọmọ wọn.
Adari ẹsin Islam yìí fi kún un pé ohun tó fún òun ní iwuri láti ṣe ohun tí iṣẹ àkànṣe yii ni lati dojú kọ ipilẹ ipenija ààbò eyi to n ti ọwọ awọn agbebon wá to sì ń sọ pé bí àwọn agbebon ohun ba kàwe, "wọn ò ní máa ṣe ohun tí wọn n ṣe yẹn".
Gumi sọ pe "ohun to wu mi lori láti ṣe eyi ni ọna àti wá ojútùú si ipenija ààbò torí gbogbo ìwà ọ̀daràn lo ni awọn oniṣẹ tirẹ ti àwọn oníṣẹ yii si wa latinu ìpéjọpọ kan taa si wa ṣàwárí pe eto ẹ̀kọ́ ni ọna àbáyọ".
Ó ni ṣe bi a ni a fẹ mu eto ẹ̀kọ́ de gbogbo igberiko ni, "kí àwọn olowo, ìjọba ìbílẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ to fi mọ àwọn àjọ àti ẹlẹgbẹ ń jẹgbẹ pa ọwọ pọ láti rii dájú pe a wọ inú igbó lọ láti wo ohun taa lè ṣe láti tọju awọn Darandaran. Nkan kékeré àmọ́ yóò seranwọ láti kọ wọn ní ẹ̀kọ́ a ó sì máa gbé ní alafia pẹlu wọn ".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ilé ẹ̀kọ́ tí Gumi kọ, wọn ní kíláàsì mẹ́fà tí wọn leè fi ṣe é ẹ̀kọ́ alakọbẹ̀rẹ̀, gírámà àti gbogbo ìgbà tí ẹ bá fẹ́ kọ onírúurú ẹ̀kọ́.
"Wákàtí mẹ́rìnlélógún ni isẹ yóò máa lọ nibẹ toripe nkan bíi ago mẹwa owurọ ni àwọn Fulani máa ń kó maalu wọn jáde ti wọn si maa n padà dé ní alẹ tàbí ìrólé. Torí náà wọn ní wákàtí méjì kí wọn tó kọ maalu jáde, a sì ni bíi wákàtí méjì si mẹta nígbà tí wọn ba de.
A ó nifẹ láti fi iná Solar síbẹ̀ kí wọn lé máa kàwé ni ago mẹ́jọ sì mẹ́wàá alẹ kí àwọn Darandaran leè lọ kabọ".
Gumi ni ni báyìí, àwọn ni ilé-ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn, "a sì tún ń kọ wọn bí wọn ṣe lè gùn nkan ìjẹ tí wọn fi ń fun awọn maalu lounjẹ".
Ó ní àwọn míì lára wọn kò tilẹ̀ nílò láti jáde lọ ra torí àwọn nkan ti ko wọn ní ti awọn agbẹ míì máa ń sọnù.
"Bi a ba leè ṣe irufẹ nkan taa ṣe yìí káàkiri Naijiria, àwọn ọmọ Naijiria yóò gbé ní alafia".















