Baba Suwe: Adesola Omidina ní òun ti bẹ̀rẹ̀ èrè Suwe Family lórí ayélujára tí orúkọ bàbá òun kò fi ní parun

Oríṣun àwòrán, Omo_Omidina/Instagram
Ọkan lara awọn ọmọ Baba Suwe, Adesola Morenikeji Ibrahim Omidina, naa ti sọrọ nipa igbe aye ati iku baba rẹ.
Nigba toun naa n bawọn akọroyin sọrọ lasiko isinku naa, Adesola ni gbogbo eeyan ni oun n ki pe wọn seun fun atilẹyin baba awọn.
O ni onisowo ni oun, ti oun si tun ni awọn oju opo lori ayelujara ti oun ti n se agbelaruge tiata, paapaa isẹ baba oun ti oun pe ni 'Suwe Family'.
- "Èmi ní mo bí àkọ́bí fún Baba Suwe àmọ́ ọmọ mi kò bá bàbá rẹ̀ rìn púpọ̀ ko tó kú"
- Ìrìn-àjò Baba Suwe pẹ̀lú àjọ NDLEA lórí bó ṣe ''yàgbẹ́ tì'' ní àtìmọ́lé
- Baba Suwe ti kú tipẹ́ ṣaájú kí gbogbo èèyàn tó mọ̀ - Àbúrò olóògbé
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Ìdí rèé ta ṣe fi pósí gbe Baba Suwe tó jẹ́ Mùsùlúmì - Aya rẹ̀ àkọ́fẹ́ ṣàlàyé
- Ẹ wo ẹni tó ń jẹ́ Suwebatu nínú ẹbí Baba Suwe àti ohun tó sọ nípa olóògbé
- Bàbá mi máa ń sunkún torí bí kò ṣe le padà ṣeré tíátà mọ́ - Ọmọ Baba Suwe
- Awuyewuye bẹ́ sílẹ̀ lórí ìlànà ìsìnkú Baba Suwe, àwọn Alfa yarí
- Baba Suwe bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ó bẹ̀rẹ̀ tíátà padà
- Irọ́ ni pé TAMPAN àtàwọn òṣèré tíátà kò tọ́jú Baba Suwe lásìkò àìsàn, àwọn bẹbẹ ta ṣe rèé - Mr Latin
- Àwọn ǹkan ti ọ̀pọ̀ ko mọ nípa Baba Suwe
- Wo àwòrán àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tó péjú síbi ìsìnkú Baba Suwe
"Emi ko ri Baba Suwe bii baba mi nigba to wa nile aye, mo rii bi alawada, mo si maa n pe ni alagbada gbogbonse (Universal Comedian).
Igbakuugba ni baba mi maa n pa eeyan lẹrin, ti mo ba si wo baba mi lasan, maa rẹrin, ti mo si ti se ọpọ akọsilẹ nipa baba mi.
Ọpọ eeyan lo maa n ni mo jọ baba mi amọ ba se sunmọra to, bẹẹ naa ni a se maa n ja, mo si nifẹ baba mi pupọ pupọ.
Gbogbo eeyan si lo le jẹri si pe mo fi ọpọ akoko mi ati igbe aye mi jin fun baba mi nigba to wa laye, amọ o wu Ọlọrun lo mu lọ."
Adesola wa fi ọwọ sọya pe oun nigbagbọ pe orukọ baba oun ko ni parun, oun si ni igbagbọ ninu Ọlọrun ati atilẹyin awọn osere tiata, alagbata fiimu atawọn oludari ere pe yoo see se.



















