Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

Àkọlé fídíò, Afeez Akintunde: Àwọn ẹbí Tula Oyo figbe tá pé kò ní ohunkohun ṣe pẹ̀lú Yoruba Nation

Awọn ọmọ Alhaji Afeez Akintunde ke gbajare tọ BBC Yoruba nipa bawọn agbebọn kan to wọ asọ ologun se wa gbe baba wọn nile lati Ọjọbọ.

Akintunde ni alaga ẹgbẹ awakọ ero NURTW tẹlẹri nilu Ọyọ, ẹsun pe o n se onigbọwọ Sunday Igboho ati fifọ ọgba ẹwọn Abolongo si ni wn ni wn fi kan an.

L'owurọ Ọjọbọ, ọjọ Kejidinlogun osu Kọkanla ọdun 2021 ni awọn agbẹbọn to wọ aṣo ologun yawọ ile gbajugbaja oloṣelu naa, ti wn si gbe lọ.

Akintunde, to tun jẹ alaga tẹlẹri fun ẹgbẹ awakọ, NURTW nilu Ọyọ, ti awọn eeyan mọ si 'Tula Ọyọ', ni awọn ologun gbe lọ lai darukọ ibi ti wọn ti wa tabi ṣe afihan iwe to fun wọn laṣẹ lati gbe igbesẹ naa.

Ọkan lara awọn ọmọ Akintunde to ba BBC Yoruba sọrọ, Alhaji Afeez Akbar ṣe alaye pe, ni nnkan bi i aago meje aabọ owurọ ni iṣẹlẹ naa waye ni ile wọn to n bẹ nilu Ọyọ.

O ni baba oun ro aṣọ mọ idi lasiko to n mura lati wọ ile iwẹ ni awọn afurasi aṣoju ileeṣẹ ologun to di ihamọra ogun naa ya wọle.

O ni kete ti wọn wọle ni wọn nawọ gan Alhaji Akintunde lai se ayẹwo ohunkohun ninu ile naa.

Bakan naa ni ọmọ rẹ obinrin ni baba oun ni aisan ẹjẹ riru, ti oju si n dun, ti wọn ko si jẹ ko ri oogun lo lati igba ti wọn ti gbe lọ.

Obinrin naa fikun pe iya oun sẹsẹ ọmọ kan tan ni, ko si tun dara ko se ọfọ ọkọ, ti wọn si n rawọ ẹbẹ sawọn agbofinro lati tu baba wọn silẹ.

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ologun ni Ibadan, ọgagun Iweha, o ni awọn ko tii gbọ nipa isẹlẹ naa, oun yoo si fi iwadi opun ransẹ si awọn akọroyin laipẹ.