Femi Fani-Kayode: Wákàtí mẹ́fà ààbọ̀ ni EFCC fi gbà mí ní àlejò pẹ̀lú àpọ́nlé àti ìjáfáfá

Oríṣun àwòrán, Instagram/realffk
Minisita nigba kan fun igbokegbodo ọkọ ofurufu ni Naijiria, Femi Fani-Kayode, ti sọ pe ajọ EFCC ko mu oun si ahamọ.
Ninu ọrọ kan ti Fani-Kayode kọ si ori ayelujara Instagram rẹ ni alẹ ọjọ Iṣẹgun lo ti ṣalaye pe, ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, kọ iwe si oun lati yọju si ọfiisi rẹ.
Eyi si lo mu ki oun wọ ọkọ baalu wa si ipinlẹ Eko lati ṣe bẹẹ.
Fani-Kayode sọ pe ni nkan bi aago meji ọsan ni oun de ọfiisi naa, ti oun si kuro ni aago mẹjọ abọ alẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Kọmísánà ọlọ́pàá tú àṣírí bí ọmọ Rahmon Adedoyin ṣe ju òkú Timothy Adegoke sígbó, tó na pápá bora
- Wọ́n ní ajé wà lárá ọkọ mi ní wọ́n ṣe lò ó - Opó Timothy Adegoke gbarata
- Ẹ lọ san ₦20bn owó ìtanràn fún Sunday Igboho títí January - Iléejọ́ fọnmú fún DSS
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ EFCC mú Femi Fani-Kayode?
- Kò sí ìfẹ̀míṣòfò kankan ní Lekki Too Gate, àlọ́ àpamọ̀ lásán ni èsì ìgbìmọ̀ EndSARS - Lai Mohammed
- Awuyewuye súyọ lórí fídíò òkú Baba Suwe tó lu ayelujára pa
- Bí àyẹ̀wò òkú Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU tó kú sílé ìtura, ṣe wáyé rèé
- Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì síwájú torí kò sí atúmọ̀ èdè Yorùbá
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
O ni pẹlu apọnle ati ijafafa lẹnu iṣẹ ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa fi ba oun ṣe.
Ọsan ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade pe ajọ EFCC mu Fani-Kayode fun ẹsun iwe yiyi lati fi tan ile ẹjọ nipa eto ilera rẹ.
Fani-Kayode n koju igbẹjọ ẹsun kiko owo ilu jẹ lọna aitọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post

Ìròyìn tó gbòde kan ní pé ọwọ́ àjọ EFCC ti tẹ Femi Fani Kayode
Laipẹ ni iroyin gba ori ayelujara kan pe ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti tẹ Ọgbeni Femi Fani-Kayode.
Iroyin naa ni pe EFCC pe e lati fọrọ wa a lẹnu wo lori akọsilẹ eto ilera ti wọn ni pe o jẹ ayederu to se ki o le fi sa lasiko to n jẹ ẹjọ nile ejẹ giga ipinlẹ Eko.
Ileese amohunmaworan Channels ti fi idi ọrọ yii mulẹ.
- Naijiria yóò dojúrú tí Buhari bá tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ - Ẹgbẹ́ àpapọ̀ l‘Ókè Ọya
- Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l‘Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho
- "Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"
- Buhari, fi Sunday Igboho sílẹ̀, kí ìṣọ̀kan le padà sí Naijiria - Oluwo
- Wo nǹkan mẹ́jọ tí o lè má mọ̀ nípa Baba Suwe tó dolóògbé
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
Iroyin naa ni pe nkan bii aago kan ọsan ni Femi Fani Kayode de si ọgba EFCC to wa nipinle Eko pẹlu agbẹjọrọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Custodian of culture
Ajọ EFCC ni pe awọn yoo fi atẹjade sita ni kete ti ifọrọ wanilẹnuwo naa ba yọri sibi kan.
Koko ẹjọ naa tẹlẹ ni pe wọn fi ẹsun kan Fani Kayode pe o se magomago owo to le ni bilionu merin o le ọgọrun un mẹfa naira .
Adajo Daniel Osiagor nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ni igbẹjọ naa wa niwaju rẹ.
Ni ọjọ kẹtala, osu kẹwaa ni Adajo naa ni ki Femi Fani Kayode san igba egbẹrun naira gẹgẹ bii owo itanran pe ko yọju niwaju ile ẹjọ bi o se yẹ,.
Adajo ni ti ko ba san owo itanran naa ki wọn da beeli idure re pada.
Saaju ni wọn ni minista naa ti fi iwe ransẹ pe dokita rẹ ni ko sinmi sile ko ma jade nitori ilera rẹ



















