Sunday Igboho: Oluwo ní káwọn Ọba, àgbààgbà Yoruba rọ Buhari kó tú Igboho sílẹ̀

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti rọ awọn lọbalọba,awọn agbaagba ati awọn eekan ni ilẹ Yoruba lati gbera lọ ba Aarẹ Buhari lori ọrọ Sunday Igboho.
Oba Akanbi fi ero re lede ninu atejade to ti pe fun itusilẹ ajijagbara fun ilẹ Yoruba Nation, Sunday Igboho naa.
O ni itusilẹ Sunday Igboho yoo mu ilọsiwaju ati iṣọkan ba Naijiria gẹgẹ bi orilẹede kan ti ko le e yapa.
- Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà ń ṣèdárò Baba Suwe tó jáde láyé
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
- ''Ó burú jáì pé Ramon Adedoyin tí akẹ́kọ̀ọ́ kú sílé ìtura rẹ̀ tún ń sọ̀rọ̀ lákàtà ọlọ́pàá''
- "Davido kò ran èmi gbajúmọ̀ lọ́wọ́, ọmọ òrukàn ló fẹ́ kó ₦250 fún"
- Ìjọba fẹ́ pa mí torí àbọ̀ ìwádìí ìkú olùwọ́de EndSARS ní Lekki - Adegboruwa figbe ta
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- Ìyàwó Adedoyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe kú sílé ìtura ọkọ rẹ̀ ní Ile Ife
- Ọlọ́pàá dóòlà òṣìṣẹ́ iléèṣẹ́ 'Pure Water' méje tí ajínigbé gbé sálọ ní Kwara
- Rúdurùdu nílé aṣòfin l‘Ogun, Igbákejì olórí ilé ní wọ́n lo ayédèrú ìbuwọ́lù òun láti gbé ₦50m jáde
- Daddy Freeze pe ọmọ David Oyedepo níjà lórí ìdí tó fi ri bíbélì 15 mọ́lẹ̀ sínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners l'Amerika
Bakan naa lo kesi awọn lọbalọba kaakiri ilẹ Yoruba lati gbimọpọ lori ọna ati fi Sunday Igboho silẹ, to si ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ''Ọmọ wa''.
Oluwo ni iṣọkan Naijiria lo jẹ oun logun ati wi pe itusilẹ Sunday Igboho yoo dẹkun rudurudu ati ipe fun iyapa to tan ka ile, ka oko ni Naijiria.
O tun kesi Aarẹ Buhari pe ko bun iyi fun awọn lọbalọba ni ilẹ Yoruba ati awọn eekan ti yoo gbera wa ba a, nitori eyi yoo safihan fun awọn ọmọ Yoruba ni ile ati lẹyin odi pe iṣọkan Naijiria jẹ wa logun.
Oba Akanbi fikun un pe ki ijọba apapọ ni Naijiria jiroro pẹlu ijọba ilẹ Benin Republic, lọna ati ri pe Igboho pada si Naijiria lai si ọrọ igbẹjọ mọ.
O ni eleyii yoo tun jẹ ki ọpọlọpọ ololufẹ iṣọkan Naijiria gberasọ ni ilẹ Yoruba.
''Ariyanjiyan ati aigbọraeniye to n waye lori ọrọ Sunday Igboho to wa ni igbekun yoo dopin, ti awọn oriade ni ilẹ Yoruba, to fi mọ awọn agbaagba, ba le gbera lọ si ọdọ Aarẹ Buhari.''
''Nitori ọmọ wa ni Sunday Igboho bi o tilẹ jẹpe o ti ṣe awọn aṣiṣe kan nigba to n lọgun fun idasilẹ Yoruba Nation.''
''Awọn aṣiṣe to ṣe yii ko jẹ ki imọ rẹ lori itusilẹ ilẹ Yoruba kuro lara orilẹede Naijiria wa si imuṣẹ.''
''Nitori naa, mo rọ awọn ti ọrọ kan, ki wọn fi imọ ṣọkan, ki wọn si gbera lọ si ọdọ Aarẹ Buhari lati beere fun itusilẹ Sunday Igboho ni igbekun to wa ni Benin Republic.''
''Ti aarẹ Buhari ba gba ọrọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba yii yẹwo, yoo mu ilọsiwaju ati iṣọkan ba orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ẹyọ kan.''
''Ijọba apapọ nikan lo le e gba Sunday Igboho silẹ lọwọlọwọ bayii nitori a gbọdọ doola ẹmi ọmọ wa .''
''Titu Igboho silẹ lai si ọrọ ileẹjọ nibẹ mọ yoo bu iyi kun ijọba orilẹede Naijiria, eyi ti yoo jẹ ilọsiwaju ati igbelarugẹ''.
Ọba Akanbi wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati fi ifẹ han si ara wọn gẹgẹ bi orilẹede kan ati ẹya kan ki ohun gbogbo le rọrun pẹlu itẹsiwaju fun orilẹede Naijiria.

"Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho/Instagram
Agbẹjọrọ Sunday Igboho, Pelumi Olajengbesi ti sọrọ nipa ifẹ to wa laarin ẹya Igbo pẹlu bi awọn eekan ni ilẹ Igbo ṣe parapọ lati lọ ba Aarẹ Buhari lori ọrọ Nnamdi Kanu to wa ni panpẹ Ajọ DSS.
Olajengbesi ti wa ke si gbogbo awọn eekan ni ilẹ Yoruba lati kọ ẹkọ lara ẹya Igbo lori ọrọ Sunday Igboho.
Ninu atẹjade kan ti Olajengbensi fi soju opo ayelujara rẹ, lo ti sapejuwe bi awọn eekan ni ilẹ Igbo ṣe parapọ lati lọ ba Aarẹ Buhari lati bẹbẹ lori ọrọ Nnamdi Kanu to wa ni panpẹ Ajọ DSS.
- Ikú ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Timothy kú ní Hilton Hotel ní Ile-Ife - Agbẹjọ́rò Adedoyin
- Àìsàn ‘Dementia’ ló ń bá ọkọ́ mi Olu Jacobs fínra láti ọdún díẹ̀ - Joke Silva
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú kí irun pọ̀ lára obìnrin láì ṣe ọkùnrin
- Àlàyé rèé lórí ohun tó fa ìkúnsínú nínú ẹgbẹ́ Ìlana Omo Oodua
- Rúdurùdu nílé aṣòfin l‘Ogun, Igbákejì olórí ilé ní wọ́n lo ayédèrú ìbuwọ́lù òun láti gbé ₦50m jáde
- Mi ò pààyàn rí láyé, mi ò kí ń ṣe afini ṣòògùn owó, ẹ jọ̀wọ́ dúró dé ìwádìí Ọlọ́pàá - Rahmon Adedoyin tó ni hòtẹ́ẹ̀lì
Ninu ọrọ rẹ, o sapejuwe bi eekan ni ilẹ Igbo to jẹ aṣofin ati minisita ni igba ijọba alagbada akọkọ, Oloye Mbazulike Amaechi ṣe gbera gẹgẹ bi asaaju pẹlu awọn eekan miran lati lọ ba aarẹ Buhari.
O fikun wi pe pẹlu bi Nnamdi Kanu ṣe ri ati awọn ẹsun ti wọn fi kan an, awọn adari ati eekan ni ilẹ ẹya Igbo pe Kanu ni ''Ọmọ Wa''.
Amọ, Olajengbesi ni ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn adari ni ilẹ Yoruba ati awọn eekan, bakan naa lori ọrọ Sunday Igboho.
''Awọn eekan ni ilẹ Igbo ko bẹru pe ki awọn eniyan fi wọn ṣe yẹyẹ lori ọrọ Nnamdi Kanu, wọn dide gẹgẹ bi ẹya ti ọrọ wọn ṣe ọkan ti wọn si ni ifẹ ara wọn.''
''Bi o tilẹ jẹ pe awa Yoruba ni asa ati iṣe to wuyi amọ ko si ifẹ laaarin ara wa nitori awọn agba ilẹ Yoruba ti safihan rẹ lori ọrọ Sunday Igboho, ti ko si si ifimọṣọkan lori ọrọ rẹ.''
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
''Ko si ọrọ gboogi lati ẹnu awọn adari naa, wọn wa da Sunday Igboho nu bi ọmọ orukan.''
''Awọn agbaagba ni ilẹ Yoruba kọ ẹyin si bi o ti lẹ jẹpe Igboho ko ṣe daadaa to, ifẹ awọn Yoruba lo n ja fun.''
Agbẹjọro naa wa kesi awọn agbaagba ni ilẹ Yoruba lati kẹkọ lara ẹya Igbo to ti fi ipo asaaju han lori iṣọkan ati ṣiṣe iṣẹ pọ gẹgẹ bi ẹya kan naa.
Bakan naa lo ni awọn eekan ni ilẹ Yoruba ni ọkunrin ati obinrin to fi mọ awọn adari ẹsin, gbọdọ parapọ lati ṣe ohun to tọ lori ọrọ Sunday.
O ni paapaa awọn ti aarẹ Buhari ma n gbọ ọrọ si lẹnu ni ilẹ Yoruba gbọdọ fihan lasiko yii pe ọmọluwabi ni wọn ati pe wọn fẹran ara ilu.






















